Ogbologboo ajinigbe ati ọmọ ẹgbẹ okunkun ni mi, aimọye eeyan la ti pa- Romance

Monisọla Saka

Ogbologboo janduku agbebọn, to tun n ṣiṣẹ ajinigbe, Kufre, ti inagijẹ ẹ n jẹ Romance, lo ti ṣe bẹẹ ko si panpẹ awọn agbofinro ni ẹka ti wọn ti n gbogun ti iwa ijinigbe ati ẹgbẹ okunkun ṣiṣe nileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Cross River.

Gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin CrossRiver Watch ṣe sọ, nirọlẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii, lọwọ tẹ janduku ọhun lẹyin toun atawọn agbofinro jọ fija pẹẹta lasiko ti wọn doju ibọn kọ ara wọn.

Ninu koto giriwo kan ti wọn gbẹ sẹyin ileewe giga fasiti ipinlẹ naa, Cross River State University (UNICROSS), ti afurasi yii saaba maa n fi ara pamọ si ni wọn ti fi panpẹ ofin gbe e.

SP Ogini Chukwuma, ti i ṣe adari awọn ikọ ti wọn n gbogun ti ẹgbẹ okunkun ṣiṣe ati ijinigbe, lo ko awọn eeyan ẹ sodi lọ sibẹ. Awọn agbofinro ṣalaye pe afurasi yii ti bẹrẹ si i ka boroboro, o si ti n jẹwọ awọn iwa laabi to ti hu sẹyin. Gbogbo awọn to ti ji gbe, awọn eeyan jankanjankan ti wọn nifọn leeekanna, awọn olukọ fasiti, Dokita alabẹrẹ, iyawo ọkunrin akọroyin kan atawọn mi-in bẹẹ. Bakan naa lo tun jẹwọ pe oun ti pa awọn eeyan meji kan, Dede ati Papa lọdun 2020.

Ọkunrin yii lawọn agbofinro ti n wa latọjọ to ti pẹ. Opọ awọn ọmọ ẹyin ẹ ni wọn ku pẹlu bi wọn ṣe fara gba ọta ibọn, ti wọn si ti ṣe bẹẹ dagbere faye nibi toun atawọn agbofinro ti doju ibọn kọ ara wọn lasiko ti wọn n gbiyanju lati ru u jade nibi to fara pamọ si.

Ni kete tọwọ ba afurasi yii ni wọn ti gbe e ju janto sinu ọkọ.

Wọn ni iwadii ṣi n tẹsiwaju, ati pe gbara tawọn ba pari iwadii lawọn yoo foju afurasi naa ba ile-ẹjọ.

Leave a Reply