Ọlawale Ajao, Ibadan
Lẹyin ti ọmọdebinrin kan, Oriyomi Gboyega, ku iku gbigbona pẹlu bo ṣe gan mọ ina ilẹntiriiki, to si gbabẹ dero ọrun, awọn amookunṣika ẹda ko tun jẹ ki oku ọmọde yii faraare sun si saaree, niṣe ni wọn tun fi ada ge ọwọ rẹ mejeeji lọ.
Kayeefi to wa nidii iṣẹlẹ yii ni pe ọwọ aladuugbo awọn obinrin ọmọọdun mẹtala ọhun ni wọn ti ba oku ẹ lẹyin ti wọn ti ge ọwọ ẹ mejeeji lọ, eyi lo si sọ aladuugbo rẹ kan, Mustapha Ogidan, di ẹni ti wọn fura si lori iwa ọdaran naa, nitori ọwọ ẹ ni wọn ti ba oku ọmọdebinrin yii.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ f’ALAROYE, Alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Ọmọlọla Odutọla, sọ pe laarin oruganjọ lawọn fijilante to n ṣọdẹ adugbo kiri deede ka a mọ inu igbo nibi kan labule kan ti wọn n pe ni Igode.
O ni nigba ti wọn sun mọ Ogidan ni wọn ri i pe ẹru kan lo waa gbe ju si ẹgbẹ odo kan nibẹ. Bẹẹ ni kinni naa ki i ṣe ẹru lasan, oku Oriyọmi, ọmọ aladuugbo rẹ lo fi ẹní yí kítíkítí bii igba teeyan ba pọn bọ̀ọ̀lì sinu bébà, to lọọ gbe e ju sinu igbo, leti odo Igbosoro, labule Igode nibẹ.
Iyẹn ni wọn ṣe ta awọn agbofinro lolobo ni teṣan ọlọpaa to wa labule ọhun.
Iwadii awọn ọlọpaa lo ṣawari iya ọmọ naa to n jẹ Peace Adegboyega, ẹni to fidi ẹ mulẹ pe ina ilẹntiriiki lo gbe ọmọ oun ni nnkan bii aago mẹwaa aarọ kọja ogun iṣẹju lọjọ Ẹtì, Furaidee, ọjọ kọkandinlogun (19), oṣu yii, to fi dero ọrun ọsan gangan.
Abilekọ Peace sọ pe eto ti awọn ọkunrin adugbo ṣe ni pe ki wọn sinku ọmọ oun laaarọ ọjọ keji to ku, ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ f’oun pe oku ọmọ ọhun ti poora nibi ti wọn tẹ ẹ si, laimọ pe Ogidan lo ji oku naa gbe.
Gẹgẹ bi SP Odutọla ṣe ṣalaye siwaju, “Nigba ti awọn ọlọpaa bi ọkunrin yii leere ohun to mọ nipa iku ọmọ yẹn, o ni oun kọ loun pa a, bẹẹ ni ki i ṣe oun loun ge e lọwọ, ṣugbọn baba ọmọbinrin naa to n jẹ Sunday Adegboyega, lo bẹ oun lọwẹ lati ba oun sinku ọmọ rẹ naa.
“Nigba ti awọn ọlọpaa lọọ tu ile afurasi ọdaran yii wo pẹlu iwe aṣẹ ijọba, iyalẹnu nla lo jẹ pe ibọn ilewọ oyinbo meji pẹlu ọpọlọpọ oogun abẹnugọngọ ni wọn ba nibẹ”.
Ọwọ awọn agbofinro tun ti tẹ awọn Hausa mẹta ti wọn ba Ogidan gbẹlẹ ibi to fẹẹ bo oku ọmọ ọlọmọ mọ, awọn mẹrẹẹrin si ti n ṣalaye ohun ti wọn mọ nipa bi wọn ṣe ge ọwọ mejeeji lara oku ọmọbinrin ẹni ọdun mẹtala naa, nigba ti iwadii awọn ọlọpaa ṣi n tẹsiwaju.