Ọgọfa awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun lawọn ọlọpaa Ogun ko loteẹli kan

Ọrẹoluwa Adedeji

Nibi ti ile aye dorikọ bayii, ko sẹni to mo ibi to n lọ pẹlu ẹgbẹkẹgbe ti awọn ọdọ iwoyi n ko, eyi to n sọ wọn di ika, apaayan, adigunjale, alailaaanu ati ọdaju. Iṣẹ nla ni awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun ṣe lọsẹ to kọja yii, pẹlu bi wọn ṣe lọọ dọdẹ awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun kan ti wọn kora wọn jọ bii ẹni dọdẹ ẹranko ninu igbo. Awọn ọdọ langba yii ko ri ọdun gidi kan ṣe. Wọn ko ṣọdun pe awọn ṣe aṣeyọri nileewe tabi lẹnu ẹkọṣẹ, wọn ko ṣajọyọ pe awọn ra mọto tabi pe awọn kọle olowo nla, ajọyọ pe awọn pe ogun ọdun ninu egbẹ okunkun ti wọn n ṣe ni wọn tori ẹ kora wọn jọ si ileetura kan ti wọn n pe ni Galaxy Hotel, to wa loju ọna Ibogun, niluu Ifọ, nipinlẹ Ogun, nibi ti wọn ti dana ariya, ti wọn s i n fi oriṣiiriṣii awọn nnkan to le ṣakoba fun wọn jẹgbadun nibẹ.

Ibi ti wọn ti n ṣe yalayolo pẹlu awọn ọrẹbinrin wọn ni awọn agbofinro ka awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa ti wọn to bii ọọdunrun (300) mọ, tọwọ si tẹ mẹrindinlọgọfa (116) ninu wọn, ti wọn si ko gbogbo wọn lọ si olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Eleweran, nipinlẹ Ogun.

Aaadọrin (70) lawọn ọmọkunrin naa, nigba tawọn obinrin to wa ninu wọn jẹ mẹrindinlaaadọta, (46) ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ Aye. ALAROYE gbọ pe awọn araadugbo lo ta awọn agbofinro lolobo pe awọn ọmọ ẹgbẹ Aye ti kora wọn jọ, wọn fẹẹ ṣe ayẹyẹ ogun ọdun ti wọn ti n ṣẹgbẹ naa, bẹẹ ni wọn fi iwe pe awọn kan lati darapọ mọ wọn, leyii to mu ki ero to wa nibẹ to ọọdunrun niye.

Ṣugbọn awọn ọmọ ẹgbẹkẹgbẹ yii ko mọ pe awọn ọlọpaa ti yi gbogbo agbegbe naa po, lojiji ni ikọ ileeṣẹ ọlọpaa to n gbogun ti ẹgbẹ okunkun, iyẹn Anti-Cultism  Squad, yọ si wọn lojiji, lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹjọ yii.

Wọn ya bo wọn ni nnkan bii aago meji ku iṣẹju mẹrindinlogun loruganj oru, bi wọn si ti n jade bayii, ọwọ awọn agbofinro ni wọn n jade si.

ALAROYE fọrọ wa diẹ ninu awọn tọwọ tẹ ọhun lẹnu wo, ohun ti wọn n sọ ni pe awọn kan ni wọn pe awọn wa si otẹẹli naa pe pati kan wa nibẹ tawọn fi tẹle wọn, awọn ko mọ pe ọmọ ẹgbẹ okunkun ni wọn.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Ọmọlọla Odutọla ni ti iwadii ba ti pari laọn yoo ko awọn eeyan naa lọ si kootu lati sọ tẹnu wọn.

Leave a Reply