Ogoji biliọnu Naira lawọn aṣofin fẹẹ na sori ọkọ ayọkẹlẹ ti wọn yoo lo

 Faith Adebọla

 Bi ko ba si ayipada kankan ninu eto to n lọ lọwọ nileegbimọ aṣofin apapọ ilẹ wa niluu Abuja, laipẹ sasiko yii lawọn araalu yoo bẹrẹ si i ri awọn aṣọfin agba ilẹ wa, atawọn aṣoju-ṣofin naa, ti wọn yoo maa fi ọkọ ayọkẹlẹ igbalode aganran bọginni bọginni ṣẹsẹ rin kiri, eyi ti wọn ni owo rẹ ko din ni biliọnu lọna ogoji Naira (N40 billion).

Iwadii abẹnu kan ti iweeroyin Sun ṣe fihan pe ọgọrun-un kan o le meje (107) awọn ọkọ to n dan bii awo sobi ọhun, ẹya ti Toyota Landcruiser, ti wọn ṣe lọdun 2023 (iyẹn 2023 model) ati ọtalelọọọdunrun din meji (358) ẹya jiipu Toyota Prado, toun naa jẹ tọdun 2023, ni eto ti pari lati ha fawọn ọmọ ileegbimọ aṣofin agba atawọn ọmọleegbimọ aṣoju-ṣofin ọhun.

Iwadii tun fihan pe ọkọ akanṣe mẹrin ti wọn maa ra fawọn olori ileegbimọ aṣofin mejeeji, iyẹn ti Sẹnetọ Godswill Akpabio, ti i ṣe olori awọn ṣenetọ, igbakeji rẹ, Jubrin Barawu, olori awọn aṣoju-ṣofin, Ọnarebu Tajudeen Abass, ati igbakeji rẹ, Benjamin Kalu, ko si  lara awọn ọkọ to joju ni gbese wọnyi, akanṣe ati ara ọtọ ni tiwọn.

Ọkọ akọtami meji, eyi ti ọta ibọn ko le wọle si lara, ni wọn maa ra fun awọn olori aṣofin mejeeji, Akpabio ati Abass.

Ẹ oo ranti pe lọsẹ to kọja yii ni olori awọn aṣofin apapọ ọhun kede yiyan igbimọ alabẹ-ṣekele ile naa, ti yoo maa ri si eto ipese awọn nnkan eelo tawọn aṣofin nilo, igbimọ yii, eyi ti Sẹnetọ Sunday Karimi lati ẹkun idibo Iwọ-Oorun ipinlẹ Kogi jẹ alaga rẹ, ni wọn fa iṣẹ didunaa-dura, ati rira awọn ọkọ ọhun le lọwọ.

Oriṣiiriṣii ọrọ lawọn eeyan ti n sọ lori ẹrọ ayelujara nipa awọn ọkọ bọginni olowo nla ti wọn fẹẹ ra ọhun, ọkan-o-jọkan ero si lawọn araalu ni nipa igbesẹ naa.

Bawọn kan ṣe koro oju si owo tuulu-tuulu tawọn aṣofin fẹẹ na ọhun, bẹẹ lọpọ eeyan n sọ pe igbesẹ yii ko fihan pe awọn aṣofin ati ijọba to wa lode yii bikita nipa iṣẹ ati oṣi to ba araalu finra lasiko yii.

Leave a Reply