Ogunṣua gboṣuba fawọn ọmọ Mọdakẹkẹ, o rọ wọn lati mu idagbasoke ilu ni pataki

 Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ogunṣua ti ilu Mọdakẹkẹ, Ọba Joseph Olubiyi Toriọla, ti ke si gbogbo awọn ọmọ ilu naa lorileede Naijiria ati l’Oke-Okun, lati jẹ ki ọrọ idagbasoke ilu abinibi wọn ṣe pataki si wọn nigba gbogbo.

Nibi ayẹyẹ ‘Akọraye Day’ ti ọdun 2024, ikọkandinlogoji iru ẹ, to waye lọjọ kẹrinla, oṣu Kejila ọdun yii, ni Modakeke Civic Center, ni Ọba Toriọla ti rọ wọn lati waa da oniruuru iṣẹ silẹ nile.

O ni ko si bi wọn ṣe le pẹ to lẹyin odi, ile labọ sinmi oko, niwọn igba ti alaafia si ti n jọba niluu naa ati agbegbe rẹ, ko si nnkan to ni ki gbogbo wọn ma bojuwẹyin lati waa ṣe nnkan meremere sinu ilu.

Ogunṣua gboṣuba fun ifẹ ati ifọwọsowọpọ to wa laarin awọn ọmọ ilu naa, o si ke si wọn lati mọ pe ogun kan ṣoṣo ti wọn le fi le awọn ọmọ wọn lọwọ ni ẹkọ to ye kooro, nitori naa, ki olukuluku mojuto ẹkọ awọn ọmọ wọn.

Ṣaaju ọjọ naa ni ipade oniroyin ti waye, nibi ti Dokita Adesọji Ọbayọmi, ti ṣalaye pe pupọ awọn iṣẹ idagbasoke to wa kaakiri ilu Mọdakẹkẹ, nipinlẹ Ọṣun, ko ṣẹyin alaafia ati iṣọkan to wa laarin awọn ọmọ ilu naa.

Ọbayọmi sọ pe lati ọdun 1977, ni awọn ọmọ ilu naa kaakiri agbaye ti maa n da owo papọ lati fi ṣiṣẹ akanṣe ọlọkan-o-jọkan ninu ilu naa.

O ni ko too di pe ilu kankan gbero lati maa ya ọjọ sọtọ lọdun fun ikowojọ lori iṣẹ idagbasoke niluu Mọdakẹkẹ, ti pawọ-pọ kọ ile ifiweranṣẹ (Post Office), lai rọgbọku le ijọba.

Ọbayọmi sọ siwaju pe bi awọn ọmọ ilu naa ṣe n ṣiṣẹ idagbasoke ni wọn tun n fun awọn akẹkọọ ni ẹkọ-ọfẹ, ọkan lara awọn ti wọn janfaani naa si ti wa ni ipo ọjọgbọn ni fasiti nla kan bayii.

Lara awọn iṣẹ akanṣe to ni wọn ti fi iru awọn owo ti wọn ko jọ naa ṣe kikọ aafin igbalode, agọ ọlọpaa, ileewe girama ti ilu Mọdakẹkẹ, Ogunṣua Grammar School, kootu Majisreeti, ile-ẹjọ giga ti ilu Mọdakẹkẹ, Ogunṣua Redio, kootu kọkọ-kọkọ ọja Ọlọrunṣogo ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Bakan naa ni Dokita Lasisi Ọlagunju, oniroyin pẹlu Nigerian Tribune, ṣedanilẹkọọ lori oniruuru ọna ti idagbasoke fi le ba ilu Mọdakẹkẹ.

Ọlagunju rọ awọn ọmọ ilu naa lati bẹrẹ iṣẹ agbẹ lọna igbalode, ki wọn ṣatunṣe awọn ileewe ti wọn ni, ki wọn si gbaju mọ awọn igbesẹ to le mu itẹsiwaju ba awọn ọdọ niluu naa.

Leave a Reply