Ogunṣua tuntun gbọpa aṣẹ, o ni fun idagbasoke Mọdakẹkẹ ni – Oyetọla

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Gomina ipinlẹ Ọṣun, Adegboyega Oyetọla, ti ke si gbogbo awọn ọmọ ilu Mọdakekẹ lati fọwọ sowọpọ pẹlu ọba ilu naa tuntun, Ọba Olubiyi Toriọla, ki idagbasoke ti ko lẹgbẹ le wa niluu naa lasiko tirẹ.

Oyetọla sọrọ iyanju yii lasiko to n gbe ọpa aṣẹ fun ọba tuntun naa ninu gbọngan nla ilu Mọdakẹkẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹta, oṣu Kọkanla yii.

O ki ọba ilu tuntun yii ku oriire fun anfaani to ni lati gun ori-itẹ awọn baba nla rẹ. Bakan naa lo loun mọ riri ifẹ ati irẹpọ to n jọba ninu ilu naa, eyi to faaye gba igbọpa aṣẹ naa lati waye.

Gomina gboṣuba fun Ọọni Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi, fun ojuṣe baba to ṣe laarin ilu mejeeji, nipasẹ eyi ti wọn fi n gbe papọ lalaafia.

O waa rọ awọn ọmọ ilu naa lati tubọ maa gbe papọ pẹlu ifẹ, ki wọn yago fun ohunkohun to jẹ mọ wahala to le tapo si aṣọ aala ilu naa.

Ṣaaju ninu ọrọ rẹ, Ọọni Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, ki ọba tuntun ati gbogbo awọn ọmọ ilu Mọdakẹkẹ ku oriire, o ni igba ọtun lo de sinu ilu naa.

Ọọni fi da wọn loju pe, niwọn igba ti wọn ti fi ẹni to tọ jẹ Ogunṣua, itẹsiwaju ti ko lẹgbẹ ni yoo ṣẹlẹ lasiko Ọba Toriọla nile ati loko.

O ṣapejuwe ọba tuntun yii gẹgẹ bii ẹni to fẹran awọn ọdọ, o si ke si awọn ọmọ ilu Mọdakẹkẹ lorileede yii ati loke-okun lati ṣatilẹyin fun un.

Leave a Reply