Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ikọ ẹṣọ alaabo ilẹ Yoruba nni, Amọtẹkun, ti ṣetan lati bẹrẹ iṣẹ lakọ nipinlẹ Ogun bayii pẹlu bi Gomina Dapọ Abiọdun ṣe fi ikọ naa lọlẹ l’Ọjọbọ, ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹrin, ọdun 2021 yii, ni gbagede nla to wa l’Oke-Mosan, l’Abẹokuta.
Nibi eto pataki tawọn eeyan ti n reti tipẹ, nitori eto aabo to mẹhẹ naa ni Gomina Abiọdun paapaa ti wọṣọ Amọtẹkun, to si ṣalaye ilana tawọn ẹṣọ naa yoo maa gba ṣiṣẹ wọn lai kọja ofin.
Abiọdun ran wọn leti pe ọlọpaa ibilẹ ni ikọ Amọtẹkun, eyi ti idasilẹ rẹ waye lẹyin tawọn gomina mẹfẹẹfa ilẹ Yoruba ṣepade lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu kẹfa, ọdun 2019. O ni Amọtẹkun ko si fun nnkan mi-in ju ki wọn daabo bo ilẹ Yoruba, ki wọn si ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ọlọpaa atawọn ẹṣọ agbofinro yooku, ki i ṣe pe ki wọn ri ara wọn bii ẹni to kọja ofin rara.
Ninu ọrọ Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka ti wọn fi oye olori ogun Amọtẹkun da lọla nibi ayẹyẹ naa, o ni bi ẹṣọ Amọtẹkun kan ba huwa to ta ko idasilẹ ikọ naa, Ogun lakaaye loun yoo bẹ lọwẹ si tọhun, ti yoo mu un ṣinkun kijọba too fọwọ ofin mu un.
Ọjọgbọn Ṣoyinka sọ pe kawọn Amọtẹkun ma tẹ ẹtọ araalu ti wọn fẹẹ daabo bo mọlẹ, niṣe ni ki wọn jẹ aṣoju rere ti yoo mu iṣẹ ọlọpaa ibilẹ wu ni.
Bakan naa ni kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Edward Ajogun, sọ pe awọn eeyan oun yoo siṣẹ pẹlu Amọtẹkun lati mu eto aabo lagbara si i nipinlẹ Ogun.
Ẹ oo ranti pe ijọba ipinlẹ Ogun ti wa lori ọrọ Amọtẹkun yii tipẹ, ọpọ eeyan lo si ti n sọ pe kinni naa ti n pẹ ju ki wọn too bẹrẹ, nigba ti wahala awọn Fulani ko jẹ kawọn eeyan sun dọkan, ti awọn ajinigbe tun sọ ijinigbe di orin ti wọn n kọ ọ kiri pẹlu jiji awọn eeyan gbe. Ṣugbọn ni bayii ti ikọ naa ti gbera sọ nipinlẹ Ogun, ti ijọba ti fun wọn ni mọto ati ọkada ti wọn yoo fi ṣiṣẹ, ọmọ Ogun, iṣẹ ya ni.