Monisọla Saka
Ajọ eleto idibo ilẹ wa, INEC, ti fi ibẹru wọn han l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹfa yii, nigba ti wọn ni kaadi idibo to to miliọnu ogun lo n rare lakata wọn ti ko rẹni wa gba a.
Awọn ajọ yii tun fi ẹdun ọkan wọn han si iha ko-kan-mi ti awọn eeyan kọ si iforukọsilẹ fun kaadi idibo to n lọ lọwọ.
Igbakeji adari ajọ naa, Mary Nkem, lo sọ eleyii l’Abuja lakooko ti wọn n ṣe ifilọlẹ ọkọ bọọsi bọginni fun lilọ bibọ kaadi idibo, eyi ti awọn ajọ kan ti ki i ṣe ti ijọba ti wọn n pe ni ‘The Advocacy for Civic Engagement’ ṣagbekalẹ rẹ.
Arabinrin Nkem waa ke pe awọn eeyan ilẹ Naijiria, paapaa ju lọ, awọn ọdọ, lati ri i daju pe wọn ko ipa pataki ninu yiyan olori tuntun ti yoo mu ayipada rere ba ilẹ wa, ti yoo si mu ki o tẹsiwaju.
Gẹgẹ bo ṣe wi, o ni ibo nikan lo le sọ ẹni ti yoo jawe olubori ninu eto idibo gbogbogboo ọdun 2023, ki i ṣe akitiyan ori ẹrọ ayelujara.
Nigba to n sọrọ, Nkem ni, “Iforukọsilẹ fun kaadi idibo ti bẹrẹ lati ọgbọnjọ, oṣu Kẹfa, ọdun 2021, ṣugbọn akiyesi ta a ṣe ni pe, laarin igba naa si bii ọsẹ meloo kan sẹyin, awọn eeyan o fi bẹẹ kopa rara.
“Nilẹ toni to mọ, awọn ọdọ o wulẹ sare yọju lori ẹrọ ayelujara, ki wọn kuro nibẹ gẹgẹ bi iṣe wọn tẹlẹ, ibẹ ni wọn n gbe bayii. Fun idi eyi, tẹ ẹ ba fẹẹ kan si wọn, afi kẹ ẹ lọ sibi tẹ ẹ ti le ba wọn, eleyii o si ju oriṣiiriṣii awọn ikanni ẹrọ ayelujara naa lọ.
“Amọ ṣaa o, emi fẹ ko di mimọ pe, ajọ INEC ko ṣeto idibo lori ẹrọ ayelujara o, bẹẹ la o ka esi idibo wa lori ikanni Tuita tabi Instagiraamu (Twitter tabi Instagram).
‘‘Inu apoti ibo la ti n ka ibo wa, iwe idibo to ba wọ inu apoti idibo nikan la n ka.
Nnkan ti eleyii tumọ si ni pe ki tolori tẹlẹmu jade lọọ yan olori ti wọn ba fẹ lọjọ idibo. Bẹẹ, lai si tagiiri, awo o hu, eeyan gbọdọ ni kaadi idibo rẹ lọwọ ko too le ṣe bẹẹ”.
Adari ajọ adani ti ki i ṣe ti ijọba, Advocacy for Civic Engagement, Obinna Osisiogu, ṣalaye pe eto ti awọn gbe kalẹ yii yoo mu ki o kere tan, ida ọgọta awọn ọdọ lanfaani lati le forukọ silẹ, ki wọn si gba kaadi idibo alalopẹ wọn nitori ati le dibo lọdun 2023.
Gẹgẹ bo ṣe wi, iṣẹ akanṣe ti wọn ṣagbekalẹ rẹ yii yoo mu ọrọ wahala igboke-gbodo ọkọ ti ko jẹ ki awọn eniyan ilẹ yii kan, paapaa awọn ọdọ, raaye kopa ninu eto iforukọsilẹ ati lati ri kaadi idibo alalopẹ wọn gba.