Adewale Adeoye
Gbajumọ oṣerebirin onitiata ilẹ wa nni, Iyabo Ojo, ti tun ṣi aṣọ loju eegun lori ọrọ ija ojoojumọ to n lọ laarin ẹbi Oloogbe Mohbad ati Wunmi ti i ṣe iyawo rẹ.
Ninu ọrọ ti Iyabọ Ojo sọ lori eto kan lori ẹrọ ayelujara lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun 2023 yii, lo ti sọ pe awọn dukia oloogbe ọhun kọọkan to wa nikaawọ ẹbi iyawo oloogbe naa lo n dija silẹ laarin awọn ẹbi mejeeji nigba gbogbo.
Aimọye igba ni Alagba Joseph Alọba ti i ṣe baba oloogbe ti fẹsun kan ẹbi iyawa ọmọ rẹ pe awọn gan-an ni ko jẹ ki ọmọ oun gbe ohun gidi ṣe foun latigba ti irawọ rẹ ti goke nidii iṣẹ to yan laayo.
Iyabo Ojo ni, ‘ Ki i ṣe iroyin mọ rara pe baba oloogbe yii ki i fi bo nigba gbogbo to ba lanfaani lati ba awọn oniroyin sọrọ pe iyawo ọmọ oun atawọn ẹbi rẹ ni wọn ko jẹ ki ọmọ oun ṣetọju oun nigba aye rẹ. Baba oloogbe paapaa tiẹ ti figba kan pe mi ri lori foonu, to si sọ b’awọn ẹbi iyawo ọmọ rẹ ṣe ti gbẹsẹ le awọn dukia ọmọ rẹ kọọkan, mi o fara mọ eyi rara’.
Bakan naa lo jẹ pe awọn ẹsun nla gbogbo ti baba oloogbe fi kan iyawo ọmọ rẹ ko dun mọ iyawo yii ninu rara, to si n foju ko tọ wo baba ọkọ rẹ bayii.