Ogundoyin, olori aṣofin Ọyọ, di aarẹ gbogbo awọn aṣofin Naijiria

Ọlawale Ajao, Ibadan

Olori ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ, Ọnarebu Debọ Ogundoyin, ti di aarẹ agbarijọ awọn olori ileegbimọ aṣofin lorileede yii.

Ipo yii ja mọ Ogundoyin lọwọ lẹyin ti olori wọn tẹlẹ, lati ipinlẹ Ogun,Ọnarebu Taiwo Oluọmọ, juwọ silẹ nibi idije naa.

Ogundoyin lo gba ipo lọwọ Ọnarebu Abubakar Suleiman, to jẹ olori ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Benue.

Ọdun meji ni saa ti aarẹ awọn aṣofin le lo nipo, aarin ẹkun Ariwa ati Guusu ni wọn si ti n pin in.

Ogundoyin fitan balẹ pẹlu bo ṣe jẹ aarẹ to kere ju lọ lọjọ ori ninu itan ilẹ Naijiria.

Nigba to n sọrọ, Ọnarebu Ogundoyin ṣeleri lati ṣiṣẹ sin agbarijọ ẹgbẹ awọn aṣofin naa, pẹlu erongba lati mu afojusun ẹgbẹ naa ṣẹ.

Leave a Reply