Ohun akọkọ ni lati ṣatunṣe siwee ofin ilẹ wa ti mo ba di aarẹ Naijiria-Atiku

Faith Adebọla

Oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), Atiku Abubakar, ti sọ pe oun ti fi gbogbo awuyewuye ati aigbọra-ẹni-ye to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ oṣelu naa ṣe afisẹyin teegun i fiṣọ, o loun ko ri i ro mọ ni toun, tori ko sọgbọn tawọn fi le paarọ alaga apapọ ẹgbẹ naa lasiko ti eto idibo ti wọle de tan yii, nitori bẹẹ, ọpọn idije funpo aarẹ oun ti sun siwaju, ọrọ to kan loun n mu sọ ni toun.

Atiku sọrọ yii lasiko to n dahun ibeere ileeṣẹ oniroyin Voice of America, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrin, oṣu Kọkanla yii.

Ẹ oo ranti pe awọn gomina marun-un kan ninu ẹgbẹ oṣelu naa ni wọn dẹyẹ si eto ipolongo ibo aarẹ Atiku, ti wọn si lawọn o ni i kopa tabi ṣiṣẹ fun igbakeji olori orileede wa tẹlẹri naa, latari awọn aidọgba kan ti wọn lẹgbẹ naa gbọdọ kọkọ wa iyanju si.

Lara ohun tawọn gomina yii n beere ni pe ki Alaga apapọ PDP, Sẹnetọ Iyorchia Ayu, kọkọ kuro lori aleefa na, ki wọn si mu alaga mi-in lati agbegbe Guusu ilẹ wa, igba naa lawọn yoo too ṣatilẹyin fun oludije funpo aarẹ, Atiku, to wa lati iha Ariwa orileede yii.

Gomina Nyesom Wike tipinlẹ Rivers, to jẹ lewaju fawọn gomina tinu n bi yii sọ pe ko sọgbọn ti PDP fi le jawe olubori lai si atilẹyin awọn gomina maraarun-un yii.

Nigba ti wọn beere lọwọ Atiku ohun to fẹẹ ṣe sọrọ yii, o ni:

“A o ti i yanju ọrọ naa, o ṣi wa nibẹ. Amọ ni temi, ọpọn ti sun siwaju, mi o ri i ro mọ, ko si ba mi lẹru pẹẹ. Ni ikorita ta a de yii, ko tiẹ bọ si i lati maa sọrọ yiyọ alaga apapọ ẹgbẹ nigba ti eto idibo ti wa lẹyinkule wa, asiko yii kọ la maa maa sọ’yẹn.”

Wọn tun beere lọwọ Atiku nipa erongba rẹ lati yanju iṣoro eto aabo to mẹhẹ yii, o si fesi pe ohun akọkọ toun yoo ṣe gẹgẹ bii aarẹ ni lati ṣatunṣe siwee ofin ilẹ wa lọgan, ki ofin ti yoo fawọn ijọba ipinlẹ ati ibilẹ lanfaani lati ni ọlọpaa tiwọn tete bẹrẹ iṣẹ kia.

Bakan naa lo lawọn ọlọpaa atawọn agbofinro yooku gbọdọ ri awọn nnkan eelo igbalode ati imọ ẹrọ ode-oni gba, o lawọn maa ro wọn lagbara gidi, ki wọn le koju iṣoro aabo asiko yii, tori aja iwoyi lo mọ ehoro iwoyi i le, gẹgẹ bo ṣe wi.

Leave a Reply