Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Pẹlu bo ṣe jẹ pe ọba alaye meji lawọn agbebọn, ajinigbe, tawọ si laipẹ yii nipinlẹ Ekiti, ti wọn yinbọn lu ọba kan, ti ikeji si wa nigbekun bayii, Olori pata fun ijọ Onirapada (Redeemed) Pasitọ Enoch Adeboye, ti ṣalaye pe ohun to buru gbaa ni awọn iṣẹlẹ yii. O lo ba ni lọkan jẹ pe awọn ajinigbe n ji ori ade lọ.
Ipinlẹ Ekiti ni Baba Adeboye ti sọrọ yii lọjọ Abamẹta, Satide, to kọja, nigba to ṣabẹwo si Gomina Kayọde Fayẹmi nile ijọba to wa l’Ado-Ekiti. Pasitọ Adeboye ṣalaye pe aibọwọ fun ori ade ni iwa ijinigbe to n ṣẹlẹ sawọn ọba lasiko yii, o ni iyi ati apọnle to pọ lo yẹ fawọn ọba alaye, nitori ipo pataki ti wọn wa lawujọ. To ba ṣẹ n di pe ajinigbe n yinbọn lu ọba, wọn n da wọn lọna, wọn si n ji wọn gbe lọ bayii, baba sọ pe ohun to yẹ keeyan ba ọkan jẹ si ni.
Olori sọọṣi Ridiimu yii waa ni kawọn ọmọ Naijiria ma ba ọkan jẹ ṣa, o ni ki wọn maa gbadura, nitori Ọlọrun yoo fopin si ijọba ibẹru ati jagidijagan. Baba fi kun un pe nibi ti iṣẹlẹ yii n daamu ọkan oun de bayii, oun ti fi ara oun ji lati jagun ninu ẹmi, pẹlu adura to lagbara.
Ṣe Ọba Adetutu Ajayi, Elewu ti Ewu Ekiti lawọn agbebọn kọkọ dena de, ti wọn yinbọn lu u, ki wọn too tun ji Ọba David Oyewumi, Ọbadu Ilemeso Ekiti gbe l’Ọjọbọ to kọja yii, ẹnikẹni ko si ti i ri ọba naa latigba naa titi dasiko ta a pari iroyin yii.