Ohun to buru jai ni bawọn kan ṣe n pe ede Yoruba ni ‘fanakula’-Ogunya

Ọlawale Ajao, Ibadan

Obinrin onimọ ijinlẹ kan, Ọjọgbọn Oluwafunkẹ Ogunya, ọmọ Naijiria to n kọ wọn lede Yoruba lorileede Amẹrika, ti ṣalaye idi to ṣe pinnu lati ṣiṣẹ iwadii imọ to ni i ṣe pẹlu Èṣù Láàlu.

Ọjọgbọn Ogunya, ẹni to jẹ onigbagbọ, gba pe iyatọ wa laarin eṣu ati satani to wa ninu Bibeli.

Ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu ALAROYE n’Ibadan, obinrin ara Amẹrika naa bu ẹnu atẹ lu bi ọpọ ọmọ Yoruba to wa ni Naijiria ṣe kọ iha ko-kan-mi si aṣa ati iṣe Yoruba, nigba ti awọn to wa l’Amẹrika ati nilẹ okeere gbogbo n gbe e larugẹ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “O ṣe pataki lati maa sọ ede Yoruba, ka si maa gbe aṣa wa larugẹ, ko ma baa parun. Awọn ara Amẹrika paapaa n ṣakitiyan lati gbe aṣa Yoruba ga. Bo ṣe jẹ pe wọn ki i raaye gbele to, sibẹ, wọn maa n ri i daju pe ileewe ti wọn ti n kẹkọọ ede Yoruba ni wọn fi awọn ọmọ wọn si, nitori ọpọlọpọ yunifasiti ni wọn ti n kọ ede Yoruba l’Amẹrika.

Bii apẹẹrẹ, ni yunifasiti ti emi ti n kọ awọn akẹẹkọ l’Amẹrika, o kere tan, awọn akẹkọọ ti mo n kọ lede Yoruba ni saa kọọkan ki i din ni ọgọru-un (100) niye.

Ọpọ awa ta a wa l’Amẹrika la mọ pataki aṣa ati iṣe Yoruba. Emi gẹgẹ bii ẹnikan, nnkan to ba jẹ mọ aṣa Yoruba ni mo maa n ṣe awọn iṣẹ iwadii imọ iwe mi le lori. Mo ti kọ beba lori ajẹ ri. Lọwọlọwọ bayii, Èṣù Láàlu Ògiri Òkò niṣẹ iwadii mi da le lori, mo n ṣawari ọna ti awọn onkọwe awọn ọmọ Amẹrika ti wọn jẹ alawọ dudu n gba ṣamulo Èṣù ninu awọn iwe onitan wọn”.

O fi kun un pe, “nnkan to buru jai ni bi awọn olukọ ileewe alakọọbẹrẹ ati girama gbogbo ṣe maa n pe Yoruba ni fànákúlà (ede ajejeji) ti wọn yoo si maa sọ pe awọn akẹkọọ ko gbọdọ sọ ọ.

“Mo ranti pe nigba ti mo wa nileewe girama ni Naijiria, ẹni to ba sọ ede Yoruba ninu kilaasi lasan, aṣọ ẹlẹya kan wa ti wọn maa n wọ si onitọhun lọrun, ki gbogbo aye le da a mọ gẹgẹ bii ẹni ti ko gbọ ede Oyinbo.

“Ohun ti wọn kọ si ara aṣọ yẹn ni pe “mi o le sọ Oyinbo, ẹ ran mi lọwọ”. Niṣe ni iru ẹni bẹẹ gbọdọ maa wọ ẹwu yẹn kaakiri, nigba to ba n lọ sile nikan lo maa bọ aṣọ yẹn silẹ, to ba tun ti de ileewe lọjọ keji, aṣọ yẹn lo maa kọkọ wọ, o si gbọdọ maa wọ ọ kaakiri gbogbo ibi to ba n lọ ninu ọgba ileewe bẹẹ fun odidi ọsẹ kan.

“Iru nnkan bayii ko daa, ko ran idagbasoke ede abinibi wa lọwọ rara. Orileede to ba n ṣe bẹẹ ki i ni idagbasoke nipa ti ede ati aṣa”.

O waa gba gbogbo awọn oniṣẹ akada niyanju lati fi idagbasoke aṣa Yoruba ṣe afojusun wọn ninu iṣẹ iwadii gbogbo ti wọn ba n ṣe.

O ni ki awọn obi nilẹ Yoruba naa si ri i daju pe awọn ọmọ wọn n sọ ede abinibi wọn ninu ile, ki awọn ijọba naa gbe oriṣiriṣi eto kalẹ lati ri i pe ede ati asa Yoruba ko parun.

Leave a Reply