Ọjọ Aje nidaajọ yoo waye lori ọrọ beeli Adedoyin atawọn oṣiṣẹ rẹ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Adajọ ile-ẹjọ giga ipinlẹ Ọṣun, Onidaajọ Adepele-Ojo, ti mu ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to n bọ, lati dajọ lori ẹbẹ beeli ti awọn agbẹjọro Dokita Rahman Adedoyin atawọn oṣiṣẹ rẹ, gbe siwaju rẹ.

Bakan naa ni adajọ sọ pe ni kete ti oun ba ti gbedaajọ kalẹ lori ọrọ beeli wọn ni igbẹjọ naa yoo bẹrẹ gan-an.

Adedoyin ati Adedeji Adesọla, Magdalene Chiefuna, Adeniyi Aderọgba, Oluwale Lawrence, Oyetunde Kazeem pẹlu Adebayọ Kunle ni wọn fara han niwaju adajọ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, lori ọrọ iku akẹkọọ Fasiti Ifẹ kan, Timothy Adegoke, eyi to waye nileetura Hilton Hotel and Resorts, loṣu Kọkanla, ọdun to kọja.

Nigba ti ẹjọ naa bẹrẹ lọjọ Tọsidee, Barisita Kunle Adegoke rawọ ẹbẹ si kootu lati fun un ni anfaani asiko diẹ lati le gbe iwe siwaju rẹ fun beeli olujẹjọ keje, Adeṣọla Adedeji, ẹni ti wọn ṣẹṣẹ so mọ awọn ti yoo jẹjọ.

Agbẹjọro fun olupẹjọ, M. Ọmọsun, ko ta ko arọwa agbẹjọro olujẹjọ.

Onidaajọ kootu naa, to tun jẹ adajọ agba funpinlẹ Ọṣun, Adepele Oyebọla-Ojo, sun ẹjọ naa si ọjọ Ẹti, Furaidee, lati le fun agbẹjọro awọn olujẹjọ lanfaani lati gbe iwe beeli Adeṣọla wa, ki oun le sọrọ papọ lori ẹ.

Ojo waa paṣẹ pe ki wọn ko awọn afurasi mejeeje lọ si ọgba ẹwọn ilu Ileṣa titi di ọjọ Ẹti, Furaidee.

Leave a Reply