Ọjọ Aje ọsẹ yii ni wọn yoo sinku Oriṣabunmi si Kwara

Aderohunmu Kazeem

Ọjọ Ajé, Mọnde, ọsẹ yii, ni wọn yóò sìn gbajumọ òṣèré tíátà nni, Fọlakẹ Arẹmu, ẹni tawọn eeyan tun mọ sí Orisabunmi sílùú ẹ ni Ọlla, nijọba ìbílẹ̀ Ìsìn, ni Kwara.
Ninu ọrọ ti Alhaji Fatai Dan Kazeem to jẹ ana oloogbe ba AKEDE AGBAYE sọ lo ti sọ pe gbogbo eto ti pari lori isinku òṣèré náà, ati pe ọjọ Ajé, Mọnde, gan-an ni oku obinrin ọhun yóò kuro ni Ibadan, ti wọn yóò gbé e lọ sílùú ẹ ni Ọlla, nipinlẹ Kwara.
Aarọ kutu, ní nnkan bíi aago meje, lo sọ pe gbogbo oju yóò pe, ti ẹsẹ yóò pele paapaa, ni àdúgbò Iwo road, niluu Ibadan, ti wọn yóò sì mori le Kwara, nibi ti wọn yóò ti fi eeru fún eeru, yeepẹ fun yeepẹ lọjọ ọhun kan náà.
Ni ọsẹ diẹ sẹyin ni gbajumọ òṣèré tíátà yìí jade laye lẹyin àìsàn ranpẹ to ṣe é.
Nibi ti gbogbo ayé tí n daro obinrin yii lọwọ, paapaa awọn ẹbi ẹ, ni wahala mi-ìn ti tun ṣẹlẹ nínú ẹbí wọn. Ẹni tí i ṣe ẹgbọn Oriṣabunmi, ìyẹn Steve Oniṣọla, lo ku lojiji, ohun tawọn èèyàn si n sọ ni pe boya iroyin iku aburo ẹ to gbọ lo fa a toun naa fi ku.
Gbogbo iṣẹlẹ yii ko ti ì ju bii ọjọ meji sira wọn ti Janet Ademọla, to n gbe niluu Ibadan, to jẹ aburo oloogbe naa tun fi fo sanlẹ, toun naa tun jade laye.
Eyi lo mu awọn èèyàn kan maa sọ ọ kiri pé bóyá àrùn Koronafairọọsi lo n pa wọn ninu mọlẹbi awọn Oriṣabunmi.
Ṣugbọn ki iroyin buruku yii too gbilẹ jù bẹẹ lọ ní Dan Kazeem ti ba awọn oniroyin sọrọ, ṣe oun yii naa lọkọ aburo Oriṣabunmi, iyẹn Alhaja Mama Ọlamilekan.

Ohun tá a gbọ ni pe Iya Lekan yii naa lo ku ninu awọn ọmọ ìyá wọn, nitori laarin ọsẹ kan pere lawọn mẹta jade laye.

 

Leave a Reply