Lati ọwọ Oniroyin wa
O to aadọta eeyan ti wọn pa lanaa kaakiri Naijiria, nitori iwọde ti awọn ọdọ n ṣe pe ijọba Naijira gbọdọ fi opin si awọn ọlọpaa SARS, ki wọn ko wọn kuro ni titi, ki wọn si pa wọn rẹ patapata. Ṣugbọn ina ọrọ naa jo de ori koko lanaa, nigba ti awọn ọlọpaa ati awọn ọmọọta kọ lu ara wọn, eyi to si buru ni igba ti awọn ṣọja kan ya wọ igboro Eko, ti wọn si lọ si Lẹki nibi ti awọn ọdọ naa wa, ti wọn doju ibọn kọ wọn, ti wọn pa ọpọlọpọ, ti wọn si ṣe awọn pupọ leṣe.
Ni ọwọ iyalẹta ni wahala ti kọkọ bẹrẹ ni adugbo Ojuwoye ni Muṣin, lasiko ti awọn ọmọọta kan gbegi dina fun ọga ọlọpaa (DPO) teṣan Ọlọsan, nigba tiyẹn ni oun fẹe kọja lọ sibi kan. Alaroye gbọ pe bi awọn onijangbọn naa ko ṣe jẹ ki wọn kọja ni wọn ti pada si agọ wọn, aṣe niṣe ni DPO naa lọo ko ọpọlọpọ awọn ọlọpaa wa si i. Bi wọn ti pada debẹ ni wọn yinbọn soke, ṣugbọn awọn to dena de wọn ko kuro, ni wọn ba kuku doju ibọn naa kọ wọn, eeyan mẹtadinlogun lo si ku nibẹ lẹẹkan.
Ija buruku ni awọn ọlọpaa Orile ati awọn ọdọ mi-in tun ja, nigba ti awọn ọdọ yii lọ sibẹ lati sọ pe awon ko fẹ SARS mọ, ṣugbọn to jẹ niṣe lawọn ọlọpaa naa doju ibọn kọ wọn, nitori ti wọn ni ki wọn yọ ọga wọn ti wọn n pe ni Iya Rainbow nibẹ kuro, pe o wa lara awọn ti wọn n fi awọn ọlọpaa halẹ mọ araalu, ati awọn ti wọn n gbe si ẹyin SARS. Nibi ti awọn ọdọ ati atawon ọlọpaa ti n ṣe eyi lawọn ọmọọta ti ya debẹ, lawọn ọlọpaa ba ṣina ibọn, ti awọn ọdọ si yari kanlẹ. Nigbẹyin, mẹta leeyan to ku, ati ọlọpaa kan. Nigba tawọn ọdọ naa si ri i pe ọrọ ti la iku lọ bẹẹ, wọn kuku dana sun teṣan ọlọpaa naa.
Bi wọn ti paayan ni Ketu, bẹe ni wọn paayan ni Ogolonto ni Ikorodu, ti wọn si pa awọn eyan ni Ibadan, ipinlẹ Ọyọ naa. Ṣugbọn eyi to buru ju ni ti awọn ti wọn pa ni Too-geeti ni Lẹki, Eko, nibi ti awọn ọdo naa gbarajọ si. Ijọba ipinlẹ Eko ti sare ṣe ofin konilegbele, wọn ni yoo bẹrẹ lati ago mẹrin irọlẹ, ṣugọn awọn ọmọ yii ta ku, wọn ni awọn ko lọ, ibẹ lawọn yoo wa. Bi ọjọ ṣe n lọ si ọwọ alẹ lawọn eeyan kan pa ina gbogbo agbegbe naa, wọn si yọ kamẹra to n ya fọto awọn eeyan to n lọ to n bọ ni agbegeb too-geeti yii, ko ma di pe ẹnikẹni yoo mọ ohun to ba ṣẹlẹ nibẹ.
Bi ilẹ ti ṣu daadaa ti ko sẹni to le ri ẹni keji mọ, awọn ṣọja kan de tibọn-tibọn , wọn si bẹrẹ si yinbọn lu awọn ọdọ naa laiwoju ẹni kan. Nibẹ ni pupọ eeyan ti ku, ti ọpọ si fara gba ọta ibọn. Titi di bi a ti n wi yii, a ko ti i mọ iye ẹni to ku gan-an, bẹe ni ọpọ wa ni ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun. Ọrọ naa ti di ohun ti gbogbo agbaye n da si, ti wọn si n sọ pe Ọjọ Iṣẹgun, Ọgunjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020, ni Naijria, ọjo buruku gbaa ni fun gbogbo aye, nitori ọjọ ti wọn ta ẹjẹ awọn alaiṣẹ silẹ ni.