Jọkẹ Amọri
Inu idunnu nla ni ọkan ninu awọn oṣere ilẹ wa to rẹwa daadaa nni, Oluṣọla Kosọkọ-Abina, to tun jẹ ọmọ gbajumọ oṣere nni, Jide Kosọkọ, wa bayii.
Eyi ko ṣeyin bi Ọlọrun ṣe ṣẹṣẹ fi ọmọkunrin kan ta idile naa lọrẹ lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹjọ, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, iyẹn ọjọ keji lẹyin ti oṣere naa ṣe ọjọọbi ọdun kẹtalelogoji to dele aye.
Ṣe ko kuku sẹni to mọ pe o diwọ-disẹ sinu, ayẹyẹ ọjọọbi rẹ lawọn ololufẹ rẹ n ki i fun titi di asiko yii, pẹlu bo ṣe gbe e sori ikanni Instagraamu rẹ lọjọ Abamẹta, Satide, pe oun le ọdun kan si i loke eepẹ, ti awọn oṣere ẹgbẹ rẹ, to fi mọ awọn ololufẹ rẹ atawọn mọlẹbi rẹ si n ki i ku oriire ti ọjọọbi naa, ko sẹni to rokan pe ọmọ tuntun ti detosi, ayọ si ti fẹẹ di meji lọọdẹ Ṣọla laarin ọjọ kan sira wọn.
Afi bo ṣe di ọjọ Aiku, Sannde, ti oṣere yii gbe aworan rẹ ati ti ọmọkunrin jojolo ti Ọlọrun ṣẹṣẹ fi ta idile rẹ lọrẹ sori Instagraamu rẹ, to si kọ ọ sibẹ bayii pe, ‘‘Ajọyọ nla leyi o, ọmọọba mi to rẹwa ti de. Ẹ ba mi yayọ ọmọ tuntun pẹlu bi mo ṣe ṣẹṣẹ bi ọmọkunrin lantilanti.
‘‘Ọlọrun ti jẹ olotitọ si mi, mi o si fọwọ yẹpẹre tabi oju kekere wo ijolotitọ rẹ si mi. Ogo ni fun Ọlọrun Alagbara’’.
Ohun to jẹ ki ayọ ọmọ yii tun jẹ ara ọtọ fun oṣere yii ati ọkọ rẹ ni pe obinrin ni awọn ọmọ meji to ti bi ṣaaju. Eyi to si ṣẹṣẹ bi to jẹ ọkunrin yii naa ni akọbi rẹ lọkunrin.
Gbogbo awọn oṣere ẹgbẹ ẹ ni wọn ti n ba a yọ, ti wọn si n ki i ku ọwọ lomi.
Lara awọn to ti ki Ṣọla Kosọkọ ni Adedimeji Lateef, Dayọ Amusa, Dele ọmọ wolii, Biọla Adebayọ, ti gbogbo eeyan mọ si Eyinọka. Oṣere naa kọ ọ sabẹ fọto Ṣọla pe ‘ku oriire o, Arakunrin Waheed, iyẹn ọkọ Ṣọla Kosọkọ, jagun eleyii, o si bori pẹlu bo ṣe jẹ pe oṣere naa bi ọmọkunrin.
ALAROYE gbọ pe ayọ ati alaafia ni iya atọmọ wa.