Faith Adebọla, Eko
Dipo ọjọ Mọnde, ọjọ kẹrin, oṣu ki-in-ni, tawọn ileewe pamari ati sẹkọndiri ti foju sọna fun lati wọle tẹlẹ, eyi tijọba ti wọgi le nitori ipenija arun Korona to n gberi, ijọba ti pinnu bayii pe kawọn ileewe naa wọle fun saa ẹkọ to kan lọjọ kejidinlogun, oṣu yii.
Kọmiṣanna feto ẹkọ nipinlẹ naa, Abilekọ Fọlaṣade Adefisayọ, lo kede ọjọ iwọle tuntun ọhun ninu atẹjade kan.
O ni ijọba ipinlẹ Eko ti fọwọ si i pe ki taamu keji ikẹkọọ fun ọdun 2020 si 2021 bẹrẹ ni ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejidinlogun, oṣu ki-in-ni.
Kọmiṣanna naa ṣekilọ pe kawọn obi wọn tubọ daabo bo awọn ọmọ wọn lọwọ arun aṣekupani ọhun, nipa riri i daju pe awọn ọmọ naa n lo ibomu, wọn n fomi ati ọṣẹ fọ ọwọ wọn deede, wọn si n lo kẹmika apakokoro, sanitaisa, to yẹ nigba gbogbo.
O ni ijọba yoo tubọ maa kiyesi bi ọrọ itankalẹ arun Koro ba ṣe n lọ si, gbogbo isapa ni wọn yoo si ṣe lati dena rẹ, ki ẹmi awọn ogo wẹẹrẹ naa maa baa wa ninu ewu.