Ojo n digun jale, o n ṣẹgbẹ okunkun, o tun paayan

Gbenga Amos, Ogun

‘Ojo o si nile, ọmọ adiẹ dagba’ la maa n gbọ, gẹgẹ bii oriki wọn ṣe lọ, ṣugbọn ti gende ẹni ọdun mejilelọgbọn, (32) ti wọn porukọ ẹ ni Ojo Fagbenro yii yatọ ni tiẹ o, awọn ọlọkada atawọn ero agbegbe Giwa si Oke Aro, loun n ṣe ni ṣuta, bo ṣe n fibọn ja ọkada gba, bẹẹ lo n ja wọn lole dukia, o si lọmọ ẹgbẹ okunkun pọmbele loun nigba ti ọwọ to o.

Ọga agba awọn ẹṣọ alaabo So-Safe nipinlẹ Ogun, Kọmanda Sọji Ganzallo, to fiṣẹlẹ yii to ALAROYE leti ninu atẹjade kan l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, sọ pe ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kọkanla yii, lọwọ awọn ọmọọṣẹ oun ti wọn n ṣe patiroolu lagbegbe Oke-Aro si Olambẹ, tẹ afurasi ọdaran naa. Ontaja kan to n kiri awọn ẹya ara foonu lori biriiji to wa laduugbo Abule Ẹkun, lagbegbe Giwa, lọna Ijoko, nijọba ibilẹ Ifọ, ni wọn l’Ojo yọbọn si ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ, o si ti n gba owo ati ọja ẹ kọwọ palaba rẹ too ṣegi, awọn ẹṣọ So-Safe yọ si i lojiji, ni wọn ba mu un.

Iwadii fihan pe adugbo Ija-Aga, ni Abẹkoko, lọna Iju si Iṣaga, lafurasi ọdaran yii n gbe, ko si niṣẹ meji to n ṣe ju ole jija ati janduku lọ.

Wọn lo fẹnu ara ẹ jẹwọ nigba ti wọn mu un de ọfiisi awọn So-Safe l’Oke-Aro pe loootọ loun n jale, ati pe ole loun n ja lọwọ ti wọn fi mu oun lalẹ ọjọ naa.

O lọmọ ẹgbẹ okunkun loun, nọmba tiri (3) loun ninu ẹgbẹ ‘Ẹiyẹ’ ni adugbo toun n gbe, iyẹn ni pe ipo igba kẹta loun wa.

O tun jẹwọ pe oun wa ninu awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn da ẹmi Ọgbẹni Gabriel Frank legbodo lagbegbe Iju-Iṣaga, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrinla, oṣu Kọkanla ọdun yii, lasiko tawọn n ba ara awọn fajangbọn kan.

Lara irinṣẹ ti jagunlabi yii n ko kiri ti wọn ri gba lọwọ ẹ ni ibọn agbelẹrọ pompo kan, ọta ibọn, oogun abẹnugọngọ, ati baagi agbekọrun to maa n ko awọn dukia to ba ji si.

Ganzallo lawọn ti fa Ojo le awọn ọlọpaa lọwọ lẹka ileeṣẹ wọn to wa l’Ajuwọn, ki wọn le tubọ ṣewadii to lọọrin lori iṣẹlẹ yii, ki wọn si le fi i ṣọwọ si kootu, nibi ti yoo ti gbadajọ to tọ si i.

Leave a Reply