Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Wọn ti sinku ọmọkunrin kan, Adebọwale Toromade, ẹni to padanu ẹmi rẹ lasiko ti awọn kan tẹnikẹni ko ti i mọ yinbọn lu awọn ọlọkada lorita Moro, nijọba ibilẹ Ariwa Ifẹ, nipinlẹ Ọṣun.
Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, iyẹn ọgbọnjọ, oṣu Kẹfa, ọdun yii, ni Debọwale ko awọn mọlẹbi rẹ lati agboole Olúkolò, niluu Ẹdunabọn, lọ siluu Ẹdẹ, lati lọọ ṣe mọ-mi-n-mọ-ọ pẹlu awọn mọlẹbi iyawo rẹ to ti wa ninu oyun.
Lọjọ yii kan naa ni wọn si n yan awọn oloye tuntun fun ẹgbẹ awọn ọlọkada niluu Ẹdunabọn, nigba to si jẹ pe ọmọ ẹgbẹ ọlọkada naa ni Debọwale, o ri i daju pe oun de ba wọn nibi ayẹyẹ ibura naa ni kete to kuro niluu Ẹdẹ.
Bi wọn ṣe pari ayẹyẹ ibura fun awọn oloye ẹgbẹ tuntun ni gbogbo wọn sin ọga wọn to wa lati Ileefẹ de Orita Moro, ṣugbọn bi ọga wọn ṣe lọ tan ni ibọn dun latibi ti ẹnikankan ko mọ.
Bayii lọrọ di bo o lọ o ya lọna, nigba ti nnkan si rọlẹ, wọn ri i pe ibọn ti ba Debọwale ati ọlọkada kan, ẹgbẹ si ni ibọn ti ba Debọ.
Awọn mọlẹbi rẹ gbe e digbadigba, o di ileewosan aladaani kan, latibẹ si ni wọn ti ni ki wọn maa gbe e lọ si ileewosan ẹkọṣẹ iṣegun ti Yunifasiti Ifẹ (OAUTH) niluu Ileefẹ.
Ṣugbọn ki wọn too gbe e debẹ lo ti gbekuru jẹ lọwọ ẹbọra, ti ẹkun asun-un-da si bẹrẹ ninu ile wọn ati tiyawo tuntun.
Gẹgẹ bi ẹnikan ti ọrọ naa ṣoju ẹ ṣe ṣalaye fun ALAROYE, o ni wahala ti wa nilẹ tẹlẹ laarin awọn adari ẹgbẹ ọlọkada niluu Ẹdunabọn.
A gbọ pe awọn to n dari wọn nibẹ tẹlẹ ko too di pe Gomina Ademọla Adeleke dejọba ko ṣetan lati gbejọba silẹ fun awọn oloye tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan, ṣugbọn ko sẹni to mọ orisun ibi ti ibọn naa ti wa.
Amọ ṣa, a gbọ pe awọn obi Adebọwale sọ pe awọn ko ṣetan lati ba ẹnikẹni ṣẹjọ, idi niyi ti wọn fi sinku ọmọkunrin naa lọsan-an, ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kin-in-ni, oṣu Keje, ọdun yii.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni Debọ ko de oṣibitu to fi ku, ṣugbọn ẹnikeji ti ibọn ba n gbatọju lọwọ nileewosan.
Ọpalọla fi kun ọrọ rẹ pe iwadii ti bẹrẹ lati mọ ẹni to wa nidii ibọn to ṣeku pa Debọwale naa.