Ojoojumọ lọkọ mi maa n lu mi nilukilu nitori ibalopọ, mi o fẹ ẹ mọ – Esther

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ 

Kootu kọkọ-kọkọ to wa lagbegbe Oke-Ẹda, l’Akurẹ, ni obinrin ẹni ọdun marundinlogoji kan, Esther Alexander, mu ẹjọ ọkọ rẹ, Ọgbẹni Alexander Isawa, lọ, to si bẹbẹ pe ki adajọ tu ibaṣepọ ọdun mọkanlelogun to wa laarin awọn mejeeji ka.

Lara awọn ẹsun ti olupẹjọ ọhun ka si ọkọ rẹ lẹsẹ lasiko to n rojọ ni pe ki i tọju oun atawọn ọmọ mẹrin tawọn bi.

O ni owo ara oun loun fi kọle tawọn jọ n gbe, ti oun si tun n da gbọ bukata lori awọn ọmọ. Obinrin oniṣowo ọhun ni eyi to buru ju ninu ọrọ naa ni alubami ti olujẹjọ maa n lu oun nigbakuugba ti oun ba kọ fun un ko ba oun lajọṣepọ.

Igba kan wa to ni ọkunrin naa ji ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira lara owo ti oun fi n ṣowo, eyi to kuna lati da pada titi di ba a ṣe n sọ yii. Iyaale ile yii ni oun fẹ ki kootu tu awọn ka, ki wọn si paṣẹ fun olujẹjọ ko tete waa ko ẹru rẹ kuro nile oun. Bakan naa lo ni ki adajọ paṣẹ fun un pe o gbọdọ maa san owo ileewe, ounjẹ ati itọju awọn ọmọ rẹ loorekoore.

Nigba to n dahun sawọn ibeere ti Agbẹjọro olujẹjọ, Ọgbẹni Ẹ. J. Akhagbenin, beere lọwọ rẹ, Abilekọ Esther ni loootọ lọkunrin naa san owo to to bii ẹgbẹrun marun-un aabọ Naira gẹgẹ bii owo-ori oun ki awọn too fẹra. Ṣugbọn oun ri i pe ko si ifẹ mọ laarin awọn mejeeji loun ṣe wa sile-ẹjọ lati jawee ikọsilẹ fun un.

Amofin Akande Toyin to jẹ agbẹnusọ fun olupẹjọ rọ kootu lati sun igbẹjọ siwaju ki wọn le fun akọbi tọkọ-taya naa lanfaani lati waa sọ ohun to mọ lori ede-aiyede to n waye laarin awọn obi rẹ. Aarẹ kootu ọhun, Alagba Oluwaṣẹgun Rotiba, rọ awọn mejeeji lati gba awọn ẹbi wọn laaye ki wọn ba wọn yanju ọrọ naa nitunbi inubi, nitori awọn ọmọ wọn.

Ọjọ kejidinlogun, oṣu kẹjọ, ọdun ta a wa yii, ni igbẹjọ yoo tun maa tẹsiwaju.

 

Leave a Reply