Aarẹ orilẹ-ede yii nigba kan, Oluṣẹgun Ọbasanjọ, ti sọ pe ohun to ba ni lọkan jẹ ni bi awọn janduku afẹmiṣofo ṣe wọpọ nilẹ Hausa, nibi ti Aarẹ Muhammadu Buhari ti wa.
Nibi ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe laipẹ yii ni Ọbasanjọ ti sọ pe asiko niyi fun Buhari lati wa ọna bi wahala ijinigbe, ifẹmi eeyan ṣofo to n waye ni apa Ariwa-Iwọ-Oorun ilẹ Hausa lọhun-un yoo ṣe dopin.
O ni, asiko niyi fun Aarẹ Buhari lati ṣe awọn ohun ti awọn eeyan yoo fi maa ranti asiko ijọba rẹ si rere.
Ọbasanjọ sọ pe, “Tẹlẹ ni mo ro pe mo mọ eni to n jẹ Buhari, nitori ẹni to ṣiṣẹ daadaa pẹlu mi ni, ṣugb̀ọn Buhari ti mo n ri lasiko yii yatọ sẹni ti mo mọ daadaa nigba kan. Ohun ti mo tiẹ maa n bira mi ni pe, ṣe emi ni mi o mọ ọn daadaa tẹlẹ ni abi ọkunrin yii ti yatọ.”
Ninu ọrọ Ọbasanjọ naa lo ti sọ pe ki awọn eeyan ma ṣi oun gbọ, oun ko tẹle ohun tawọn eeyan kan n gbe kiri pe ki i ṣe Buhari lo wa ni Aso Rock, ti wọn ni Jubril kan lati Sudan ni. O ni iyẹn kọ ni oun n sọ, ohun ti oun mọ ni pe Buhari naa lo wa nibẹ, ṣugbọn Aarẹ ti oun n wo yii ti yatọ si ọga ologun to mọ nnkan to n ṣe nigba to k̀ọkọ fi dari Naijiria ni.
O ni, “Mo ti kọ ọ sinu iwe nigba kan pe Buhari ti mo mọ daadaa ki i ṣe ẹni to jafafa ninu amojuto eto ọrọ aje ilu, bẹẹ ni ko ni agbara tabi oye nipa ṣiṣe eto to yẹ laarin orilẹ-ede si orilẹ-ede mi-in lagbaaye, ṣugbọn ti a ba n s̀ọ nipa eto aabo gẹgẹ bii akọṣẹmọṣẹ ologun, ẹni to le ṣe daadaa ni, ṣugbọn ohun ti mo n ri lasiko yii, niṣe lo n kọ mi lominu gidi.
“Mo lero pe yoo ṣe daadaa ni, ṣugbọn gbogbo iwa ojuṣaaju ti ijọba ẹ n ṣe yii, ohun iyalẹnu ni. Ohun ti mo si lero pe o yẹ ko maa ro bayii ni ipa rere ti ijọba ẹ gbọdọ fi silẹ ti ko ba si nipo adari mọ. Ohun to yẹ ko ti eeyan loju ni o, abi nigba ti wọn pe eeyan ni apaṣẹ agba fun orilẹ ede kan, ti awọn eeyan kan ti wọn pera wọn ni janduku afẹmiṣofo wa n ji eeyan gbe, ti wọn n da nnkan ru lẹyinkule iru Aarẹ apaṣẹ bẹẹ, niṣe lo yẹ ki iru olori bẹẹ ji loju oorun to wa.”
Ninu ọrọ Ọbasanjọ naa lo tun ti sọ pe pupọ ninu awọn gomina ni wọn ko mọ ohun ti awọn paapaa le ṣe mọ nitori ọwọ yọbọkẹ ti Buhari fi mu ọrọ aabo ni Naijiria bayii.
Nigba to n sọrọ nipa awọn ọga eleto aabo ti Buhari ṣẹṣẹ yan sipo, Ọbasanjọ ti sọ pe ki i ṣe asiko niyi lati maa jo tabi yọ nitori iyansipo awọn eeyan ọhun. O ni ko ni i pẹ ti gbogbo aye yoo ri i boya wọn yoo ṣaṣeyọri tabi kuna, gbogbo ẹ lo maa han laarin oṣu mẹfa pere.
Ninu ọrọ ẹ naa lo ti ke si Aarẹ Muhammadu Buhari, lati pese awọn ohun ija fawọn ẹṣọ alaabo atawọn ohun to le jẹ koriya fun wọn ki wọn le ṣiṣẹ wọn bii iṣẹ.