Ojowu buruku: Iyaale ile la nnkan mọ ọkọ rẹ lori nitori to n ba obinrin mi-in sọrọ lori foonu

Adewale Adeoye

Iwaju Onidaajọ Khadi Umar Sanusi Dan Baba, tile-ẹjọ ‘Sharia Court’, to wa niluu Kano, ni wọn foju iyaale ile kan, Abilekọ Hafsat Ibrahim, ba, ti adajọ si ti ni ki wọn ti i mọle. Ẹsun ti awọn alaṣẹ ijọba agbegbe ọhun fi kan an ni pe o ṣe ọkọ rẹ, Ọgbẹni Muhammed Jamiu, leṣe gidi, to si tun fi sisọọsi ge gbogbo aṣọ ode ọkunrin yii nitori to fẹsun kan an pe o n ba obinrin ajoji sọrọ lori foonu.

ALAROYE gbọ pe aipẹ yii ni wọn fọwọ ofin mu Abilekọ Hafsat, lẹyin to hu iwa ọdaju ọhun si ọkọ rẹ. Wọn ni ohun to bi i ninu ni pe ọkọ rẹ n ba obinrin ajoji kan da ọwẹkẹ lori foonu. Loju-ẹsẹ ti awo ifẹ ikọkọ to ni ọkọ oun ni si obinrin ọhun tu si i lọwọ lo ti gbeja ko o loju, ki awọn araale ibi tawọn mejeeji n gbe too ṣẹju pẹu, Abilekọ Hafsat ti la nnkan mọ ọkọ rẹ lori, ti ọkọ si ṣubu lulẹ gbalaja. Awọn eeyan ti wọn wa nitosi ni wọn sare ṣaajo ọkọ yii ko ma baa ku, nitori pẹlu bi ọkọ Hafsat ṣe ṣubu lulẹ, ṣe lo tun fẹẹ ṣe e nijamba mọlẹ nibẹ. Nigba ti ohun to ṣe fun ọkọ rẹ yii ko tẹ ẹ lorun lo ba tun wọle lọ, o ko gbogbo aṣọ t’ọkọ rẹ maa n wọ lọ sode sita, o si bẹrẹ si i fi sisọọsi ge e wẹlẹ-wẹlẹ.

Ọlọpaa olupẹjọ, Usman Shu’aibu Dala, to foju olujẹjọ bale-ẹjọ sọ f’adajọ ile-ẹjọ naa pe, ‘Oluwa mi, nitori pe olujẹjọ yii ka ẹsun agbere si ọkọ rẹ, Ọgbẹni Muhammad lẹsẹ lo ṣe ṣiwa-hu, o fọ ọ lori pẹlu irin nla kan, lẹyin naa lo tun ko gbogbo aṣọ ode rẹ bọ sita, o ge e si wẹwẹ, apapọ owo aṣọ ọhun si jẹ ẹgbẹrun lọna ọgọrin Naira. Gbogbo ohun ti olujẹjọ yii ṣe pata ni ko bofin mu, ti ijiya nla si wa  fẹni to ba ṣe bẹẹ lawujọ wa.

Olujẹjọ loun ko jẹbi gbogbo ẹsun ti olupẹjọ fi kan oun.

Adajọ ile-ẹjọ ọhun ti ni ki wọn lọọ ju Abilekọ Hafsat satimọle awọn ọlọpaa na, o sun igbẹjọ mi-in si ọjọ kọkanla, oṣu Kejila, ọdun yii.

Leave a Reply