Oju ole ree, waya ina ijọba ni wọn n ji ka tọwọ ba tẹ wọn

Adewale Adeoye

Ọdọ awọn ajọ aabo ara ẹni laabo ilu ti wọn n pe ni sifu difẹnsi, ‘Nigeria Security And Civil Defence Corps’ (NSCDC), ẹka tipinlẹ Anambra, ni awọn gende mẹrin kan wa bayii. Ẹsun ti wọn fi kan wọn ni pe won ka wọn mọ ibi ti wọn ti n ji waya ina ijọba ka lagbegbe papakọ-ofurufu ‘Chinua Achebe International Airport’, niluu Umueri.

Awọn mẹrin ọhun ni, Monday Chukwu, ẹni ọdun mẹtadinlogoji lati ilu Ebonyi, Okwudiri Nnaji, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn lati ilu Idodo-Nkanu, nipinlẹ Enugu, Agu Ikechukwu, ẹni ogun ọdun lati ijọba ibile Ehamufu-Isiuzo, nipinlẹ Enugu, ati Chinecherem Idoho, lati agbegbe Uboloafor-Udenu, nipinle Enugu.

ALAROYE gbọ pe awọn waya ina nla ti wọn maa n ri mọlẹ laarin ilu lawọn ọdaran ọhun ti jingiri sinu rẹ lati maa ji nigba gbogbo ko too di pe ọwọ tẹ wọn lọjọ kẹrin, oṣu Kọkanla, ọdun 2023 yii.

Ọga agba ajọ ọhun, Kọmandanti Edwin Osuala, to ṣafihan wọn  laipẹ yii sọ fawọn oniroyin ni olu-ileeṣe wọn to wa lagbegbe Akwa, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja yii, pe owuyẹ kan lo waa ta awọn lolobo nipa iṣẹ laabi tawọn ọdaran ọhun maa n ṣe lagbegbe ọhu. O ni gbara tawọn gbọ nipa ọrọ ọhun lawọn ti lọọ fọwọ ofin mu gbogbo wọn.

‘‘Loju-ẹsẹ ta a ti gbọ nipa wọn la ti lọọ fọwọ ofin mu wọn, a ba awọn waya ina kọọkan ti wọn ji gbe lọwọ wọn lasiko ta a gba wọn mu.

Ọga agba ọhun ni gbogbo wọn pata lawọn maa too foju wọn bale-ẹjọ laipẹ,  ki wọn le fimu kata ofin.

 

Leave a Reply