Adewale Adeoye
Ko jọ pe awọn oṣiṣẹ ileegbimọ aṣofin agba kan yoo bọ nibẹ bọrọ pẹlu bi wọn ṣe fọwọ ofin mu wọn nitori pe wọn n ji awọn ẹru to wa ni ọfiisi awọn aṣofin ko lọ.
Awọn ẹṣọ ileegbimọ aṣofin agba ilẹ wa niluu Abuja lo mu awọn eeyan naa ti wọn fẹsun kan pe ṣe ni wọn fẹẹ ji awọn dukia inu ọgba naa ko sa lọ.
Lara awọn ohun ta a gbọ pe wọn fẹẹ ji ko ni awọn ohun eelo inu ọfiisi bi: faanu, ẹrọ amuletutu, firiiji, tẹlifiṣan, redio, ẹrọ ti wọn fi n ṣe ẹda iwe atawọn nnkan olowo iyebiye mi-in.
ALAROYE gbọ pe awọn oṣiṣẹ ọhun atawọn kọọkan to jẹ pẹ awọn aṣofin ti wọn n ṣiṣẹ fun tẹlẹ ko lanfaani lati tun pada sileegbimọ mọ fun saa tuntun ti wọn ṣẹṣẹ fẹẹ bẹrẹ yii ni wọn jọ lẹdi apo pọ lati ji awọn eru ọhun ko sa lọ, ko too di pe ọwọ tẹ wọn.
A gbọ pe bi wọn ṣe fẹẹ ko gbogbo awọn dukia ijọba naa jade ninu ọgba ileegbimọ aṣofin agba lawọn ẹṣọ kan to wa lẹnu geeti ti wọn maa gba kọja beere fun iwe aṣẹ lati fi han pe loootọ awọn ẹni ti wọn n ṣiṣẹ fun gan-an lo lawọn ẹru ọhun. Nigba ti wọn ko ri iwe kankan mu silẹ lawọn ẹṣọ naa ba fọwọ ofin mu gbogbo wọn pata, ti wọn si gba awọn ẹru ijọba naa kalẹ lọwọ wọn loju-ẹsẹ.
Ọga awọn ẹṣọ to n ṣọ inu ọgba awọn aṣofin agba ọhun, Ọgbẹni Chuks Obaloje, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fawọn oniroyin sọ pe loooto lawọn ti fọwọ ofin mu awọn ọmọọṣẹ awọn aṣofin agba kọọkan atawọn oṣiṣẹ ti wọn fẹẹ ji awọn dukia ijọba to wa ninu ọgba naa, tawọn yoo si fa wọn le ọlọpaa lọwọ laipẹ, ki wọn le maa ba wọn ṣẹjọ lọ lori ẹsun ole tawọn fi kan wọn.
Bẹ o ba gbagbe, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjo kẹtala, oṣu Kẹfa, ọdun yii lawọn aṣofin agba ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan maa bẹrẹ iṣẹ wọn ni pẹrẹu, eyi si wa lara idi tawọn to fẹẹ ji awọn dukia ijọba naa ro papọ ti wọn ṣe fẹẹ tete ji awọn ẹru ijọba naa ko too di pe awọn aṣofin naa de si ọfiisi wọn.