Gbenga Amos, Ogun
Adura gidi ni ti wọn ba n sọ pe k’Ọlọrun ma jẹ ka ṣile gba o, baale ile ẹni ọgbọn ọdun kan, Isau Oluwatobilọba, ti kagbako iku gbigbona lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun yii, lọwọ ọkunrin babalawo ti wọn jọ n gbele, Idowu Talabi. Ọkunrin yii lo yọ kẹlẹ wọ yara oloogbe naa lasiko to n sun jẹẹjẹ ninu yara rẹ, lo ba yọ ada pana ti i, o ṣa a niṣaakuṣa, ọkunrin naa si ti oju oorun doju iku.
SP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, lo sọrọ yii di mimọ f’ALAROYE, ninu atẹjade kan to fi lede lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kọkanla yii. o ni iyawo oloogbe naa lo sare janna-janna waa fẹjọ sun ni ẹka ileeeṣẹ ọlọpaa ilu Ikẹnnẹ pe ki wọn waa ba oun wo ara meriiyiri toun ri, oun rori ologbo latẹ o, ọkọ oun toun fi silẹ lọọ ṣọọṣi lalẹ nigba toun dagbere fun un pe oun n lọ si iṣọ oru, inu agbara ẹjẹ loun ba a ni nnkan bii aago mẹfa idaji ọjọ keji toun de, wọn ti ṣa a pa mọle.
Wọn lariwo tobinrin naa kọkọ fi bọnu ni teṣan ni p’awọn adigunjale ni wọn maa ṣiṣẹ naa, o lawọn ni wọn lọọ ka ọkọ oun mọle loru, boya igba ti wọn o rowo gba lọwọ ẹ ni wọn ṣa a pa, lai mọ pe kokoro to n jẹfọ, idi ẹfọ lo wa.
Lẹsẹkẹsẹ ni DPO teṣan naa, CSP Ibrahim Ningi, ti paṣẹ fawọn ọtẹlẹmuyẹ ọdọ ẹ pe ki wọn tẹle obinrin yii lọ sibi iṣẹlẹ ọhun ni Ojule kẹrin, Opopona Bestway, Moro, niluu Ikẹnnẹ, nigba ti wọn si debẹ, bo ṣe royin naa ni wọn ba a, wọn ri oku ọkọ ẹ ninu agbara ẹjẹ, wọn si ri apa bi wọn ṣe fada ṣa a ṣakaṣaka to fi ku.
Amọ gẹgẹ bii iṣẹ wọn, awọn ọtẹlẹmuyẹ naa ṣe awọn akiyesi kan nibi iṣẹlẹ naa. Ṣe ẹni to ti takara ri ko too ta eree, o ti mọru irọ ti onikengbe le pa. Awọn ọlọpaa naa ni oye tawọn ri yii ko jọ ti adigunjale. Akọkọ ni pe ipo ti wọn ba oku oloogbe naa fihan pe wọn ṣa a pa mọbi to ti n sun lọwọ ni, ko si si ami pe boya o dide tabi taporogan pẹlu adigunjale kankan. Wọn tun yẹ ayika naa wo, wọn ni ko si ami pe ẹnikan ja kọkọrọ wọle, wọn lẹni to ṣiṣẹ laabi ọhun fẹsọ rin wọle ni, tọhun ko si mu nnkan mi-in kuro ninu yara naa, leyii to fihan pe ẹni ti wọn pa yii lolubi ẹda naa tori ẹ wọle. Wọn lẹyinkule lọta wa, inu ile laṣeni n gbe niṣẹlẹ yii, ni wọn ba ko gbogbo awọn ti wọn jọ n gbe ile naa lọ si agọ ọlọpaa.
Iwadii to lọọrin ti wọn ṣe ni teṣan lo jẹ ki wọn roju ọrọ, ṣe okoto irọ ki i pẹẹ ja. Idowu Talabi ni abọ iwadii wọn fori sọ, loun naa ba bẹrẹ si i wolẹ ṣun-un nigba ti wọn ni ko jẹwọ.
Wọn ni babalawo yii jẹwọ nikẹyin, o ni ki wọn ma binu, oun loun ṣa ọkunrin naa pa mọle, ada loun si fi ṣa a, amọ inu lo bi oun, oun ṣinu bi ni.
Wọn bi i pe ki lo fa ibinu ọran, o ni ko sohun meji ju pe gbogbo igba ti ọrọ bii ole, bii afọwọra ba ti waye ninu ile naa, oloogbe yii ki i naka ifura sẹni meji ju oun lọ, o loun ki i si i jale, o kan n ya oun lẹnu bo ṣe jẹ p’oun lo maa n dunrun mọ, to maa n fẹsun ole kan, eyi lo bi oun ninu toun fi pinnu pe patapata la a fọju, kuna kuna la a dẹte, oun aa gbẹmi Oluwatobi danu ni.
Nigba ti anfaani si ṣi silẹ loru ọjọ naa loun yọ kẹlẹ wọ yara wọn, oun ba a nibi toorun gbe e lọ si, ibẹ loun si ṣa a pa si to fi ku.
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti ni ki wọn fi apaayan yii ṣọwọ si ẹka ti wọn ti ṣewadii iwa ọdaran abẹle, lolu-ileeṣẹ ọlọpaa to wa l’Abẹokuta. Wọn ni iwadii ṣi n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ buruku ọhun.