Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Bi alẹ ba lẹ, aa fọmọ ayo fayo ni, lowe to gba ẹnu Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Kwara, CP Ẹbunoluwarotimi Adelesi, psc+, FISN, lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ Kẹjọ, oṣu Keje yii, nigba to n ṣekilọ fun awọn ẹgbẹ ọlọkada ati ẹgbẹ awọn onikẹkẹ Maruwa pe ti aago mẹsan-an alẹ ba ti lu, wọn o gbọdọ kẹẹfin ọkada ati kẹkẹ maruwa nita mọ.
Ninu atẹjade kan ti Alukoro ọlọpaa ipinlẹ ọhun, Ọkasanmi Ajayi, fi sita to tẹ ALAROYE lọwọ niluu Ilọrin, l’ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ yii, lo ti ṣalaye pe Kọmiṣanna ọlọpaa ni Kwara, CP Ẹbunoluwarotimi, ti ṣe ipade pẹlu alaga awọn ọlọkada ati kẹkẹ Maruwa to si ran wọn leti pe ṣaaju ni ijọba Kwara ti fofin de gigun ọkada ati Maruwa lati aago mẹsan-an alẹ titi di mẹfa idaji, ki wọn si kilọ fun awọn ọmọ wọn, eyikeyii ninu wọn tọwọ agbofinro ba tẹ to tapa sofin yii yoo fẹnu fẹra bii abẹbẹ, tori ile-ẹjọ ni awọn yoo maa tari wọn lọ.
O waa kilọ fun gbogbo awọn ọdaran ki wọn tete yi ipinnu wọn pada bayii, tabi ki wọn foju wina ofin.
Bakan naa lo ni ki gbogbo awọn olugbe ipinlẹ naa maa ṣiṣẹ oojọ wọn, ki awọn oni-kara-kata si tẹsiwaju ninu ọrọ-aje wọn lai si ifoya tabi idunkooku lati ọwọ awọn ọdaran tabi awọn agbofinro. Fun idi eyi, iwa ọdaran ni Kwara ti di afisẹyin ti eegun n fi aṣọ, ki gbogbo awọn ọdaran tabi awọn to n tẹ ofin loju tete ba ẹsẹ wọn sọrọ nipinlẹ naa.