Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta
Ai le ni suuru ati wiwa ọkada niwakuwa loju ọna marosẹ lo da ẹmi awọn akẹkọọ meji kan ti wọn jẹ ọmọ iya kan naa legbodo l’Ọjọbọ, ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹrin, ọdun 2021 yii, ni marosẹ Ṣagamu si Ikorodu, gẹgẹ bawọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣe sọ.
Alukoro TRACE, Babatunde Akinbiyi, fidi ẹ mulẹ pe ni nnkan bii aago mẹjọ aarọ ku iṣẹju mẹta ni ijamba yii ṣẹlẹ, ti awọn ọmọkunrin meji ti wọn jọ jẹ ọmọ iya ati baba kan naa padanu ẹmi wọn nigba ti ọkada wọn ṣubu sabẹ tirela, ti ọkọ nla naa si tẹ wọn pa.
Akinbiyi ṣalaye pe eeyan mẹrin lo wa lori ọkada Bajaj ti nọmba ẹ jẹ LSD 638QB. Ọmọleewe Idagba Community High School, Ṣotubọ, ati Wesley Primary School, Ogijo, ni wọn. O ni ọkan ninu wọn lo n wa ọkada naa, awọn mẹta si jokoo lẹyin rẹ.
O ni nibi ti ẹni to n wa ọkada naa ti n gba aarin tirela meji kọja lo ti ṣubu, nigba naa ni tirela ti nọmba ẹ jẹ SHR 35 XA fi taya ẹyin tẹ wọn mọlẹ.
Awọn meji ti wọn jẹ ọmọ iya kan naa, ti wọn si jẹ ọkunrin, ni wọn ku loju-ẹsẹ ti tirela tẹ wọn, bẹẹ lawọn meji yooku ṣeṣe, ṣugbọn wọn ko ku.
Mọṣuari ọsibitu Ọlabisi Ọnabanjọ to wa ni Ṣagamu, ni wọn ko awọn oku naa lọ gẹgẹ ni Akinbiyi ṣe wi, ibẹ naa ni wọn ko awọn meji to ṣeṣe lọ fun itọju.