Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ajọ ẹṣọ alaabo ṣifu difẹnsi, ẹka ti ipinlẹ Kwara, ti mu ọkunrin kan to n jẹ Umar Ibrahim niluu Ilọrin, fẹsun pe o ji ọkada gbe lagbegbe lfẹsowapọ Oke, Oko Olowo, n’llọrin.
Ọjọ Ẹti, Furaidee, to lọ yii ni agbẹnusọ ajọ ṣifu difẹnsi, Ọgbẹni Babawale Zaid Afolabi, fi atẹjade sita pe ọwọ ba Umar Ibrahim nibi to ti lọọ ji ọkada gbe lagbegbe Okoolowo.
Gẹgẹ bo ṣe wi, o ni ṣe ni ọdaran naa wọle Aminu Ibrahim lagbegbe Kanike, loruganjọ, to si ji ọkada ọhun, lo ba na pápá bora. Ọjọ Aje, Mọnde, ọṣẹ yii, ni ọwọ tẹ ẹ, ti wọn si gbe e wa si ọfiisi ajọ ẹsọ alaabo niluu Ilọrin.
Afọlabi tẹsiwaju pe lẹyin ọpọlọpọ iwadii, o han pe afurasi ọhun wọ ile Ibrahim, o si ji ọkada Bajaj, aago ọwọ, foonu i-tel kan ati ẹgbẹrun mẹjọ nairagbe.
Ọga ajọ ṣifu difẹnsi ni Kwara, Ọgbẹni Makinde Iskil Ayinla, ti pasẹ pe ki wọn ṣe ẹkunrẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa, ki wọn si foju afurasi naa ba ile-ẹjọ laipẹ.