Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ọkan lara awọn akẹkọọ ileewe Ataọja High School, to fara pa ninu ijamba ọkọ to waye niluu Oṣogbo nirọlẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọse yii, Akinọla Damilọla, ti jade laye.
Gẹgẹ bi ALAROYE ṣe gbọ, ni nnkan bii aago mẹta kọja ogun iṣẹju nirọlẹ ọjọ Aje, niṣẹlẹ naa ṣẹlẹ lagbegbe November 27 Interchange, teeyan ba ti kọja Ataọja Secondary School, Oṣogbo.
Mọto meji; Toyota Corolla alawọ eeru to ni nọmba MUS 571 GB, ati Volkswagen Vento, alawọ ewe to ni nọmba LEM 478 TK pẹlu ọkada Bajaj Boxer alawọ pupa kan to ni nọmba SGB 633 QJ, ni fori sọ ara wọn.
Ere asapejude ti awakọ Toyota Corolla naa, Ọpẹyẹmi Ogunwumi, n ba bọ latọna Ṣẹkọna la gbọ pe o mu un kọ lu ọkọ Vento lojiji, ti iyẹn si padanu ijanu rẹ, to mu un kọ lu ọlọkada latẹyin.
Loju-ẹsẹ ni wọn gbe awọn maraarun ti wọn fara pa ninu ijamba naa lọ sileewosan UNIOSUN Teaching Hospital, ṣugbọn lalẹ ọjọ Iṣẹgun ni ọkan lara wọn, Damilọla, jade laye.
Alukoro fun ajọ ẹṣọ ojupopo l’Ọṣun, Agnes Ogungbemi, ṣalaye pe awọn yooku ṣi n gba itọju lọwọ, nigba ti wọn ti ko awọn mọto naa pẹlu ọkada lọ si agọ ọlọpaa to wa ni Ataọja.