Ọlawale Ajao, Ibadan
Agbọ-sọgba-nu ni iku ọdọmọkunrin adẹrin-in poṣonu to fi ilu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ, ṣe ibujoko nni, Tobi Owomoyela, ti gbogbo eeyan mọ si Comedian Peteru. Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kejila, ọdun yii, ni oṣere naa mi imi ikẹyin lẹyin aisan jẹjẹrẹ ifun (colon cancer) ti wọn lo ti n yọ ọ lẹnu fun igba pipẹ.
Ẹnikan to mọ oṣere naa daadaa to ba akọroyin wa sọrọ ṣalaye pe o to ọjo mẹta ti aisan naa ti n ba a finra, ṣugbọn Owomoyela jẹ ọmokunrin to ṣọkan akin gan-an, bi ki i baa si ṣe awọn to sun mọ ọn, wọn ko le mọ pe iru nnkan bẹẹ n ṣe e nitori ko gbe e soju rara. O ni pẹlu bi aisan naa ṣe wa lara rẹ ni yoo tun tiraka lati lọ si ode ti wọn ba pe e si, ti yoo si tun dẹrin-in pẹẹkẹ awọn eeyan.
Ṣugbọn lẹnu ọjọ mẹta yii ni aisan naa da a gunlẹ gidigidi, ko too di pe o pada waa ja si iku l’Ọjọruu, Wẹsidee.
Ohun to mu ki ọrọ naa buru ni pe ko ti i ju oṣu kan lọ ti wọn sinku baba ọmọkunrin ti gbogbo eeyan fẹran pẹlu bo ṣe maa n fi ẹfẹ rẹ sin awọn eeyan jẹ, ti awọn ololufẹ rẹ si maa n gbadun rẹ gidigidi yii ku. Bakan naa lo jẹ pe Tobi yii ni ọmọkunrin kan ṣoṣo ti awọn obi rẹ bi. Olowomoyela yii ni wọn lo ṣẹṣe n dide bọ gẹgẹ bii adẹrin-in poṣonu, to si tun maa n ṣe alaga nibi awọn ayẹyẹ lọlọkan-o-jọkan.ṣugbọn to ti ba ọpọlọpọ awọn to lorukọ nidii iṣẹ amuludun ṣịṣẹ pọ, to si gbajumọ daadaa, paapaa ju lọ niluu Ibadan.
Ọpọlọpọ awọn oṣere, awọn adẹrin-in poṣonu ẹgbẹ rẹ ni wọn ti n daro iku Peteru bi gbogbo eeyan ṣe maa n pe e. Lara wọn ni adẹrin-poṣonu obinrin ti gbogbo eeyan mọ si Lepacious Bosẹ. Pẹlu ibanujẹ lọmọbinrin naa fi kọ ọ sori ikanni re pe, ‘‘Ẹlomi-in ti tun ku. Niṣe ni awọn iroyin iku bayii maa n mu ko rẹ mi wa. Iru ki leleyii, o ti su mi, o fun ara mi gbẹ. Awọn iroyin ibanujẹ leeyan kan n gbọ lọtun-un losi, eleyii buru jai, Ọlọrun Ọba, o o si ba wa fopin si gbogbo awọn iṣẹlẹ ibanujẹ ati irora ọkan yii lasiko yii. Niṣe lo si da bii pe asiko teeyan fi wa ninu ibanujẹ waa ju asiko ti inu eeyan dun lọ.
”Mo fẹẹ sun fun igba pipẹ, boya nigba ti mo ba fi maa taji, gbogbo nnkan yoo ti pada si bo ṣe yẹ ko wa.’’ Bayii ni oṣere naa kọ ọ tẹduntẹdun sori ikanni rẹ.
Bakan naa ni oṣere ilẹ wa to fi ilu Ibadan ṣe ibugbe nni, Muyiwa Ademọla naa ti ṣedaro ọkunrin alawada yii pẹlu ohun to kọ sori ikanni rẹ pe, ‘‘Eleyii jẹ oogun to koro pupọ lati gbe sẹnu, Bawo ni ọmọkunrin oniwa daadaa yii yoo ṣe waa fi aye silẹ ni iru akoko bayii’’.
O waa pari ọrọ rẹ pẹlu arọwa pe’ ẹ jọwọ, ẹ jẹ ka maa ṣe daadaa sira wa, nitori ko si ẹni to mọ ohun ti onikaluku n la kọja. Mo gbọ pe aisan jẹjerẹ lo pa Peteru. O n la ohun to lagbara bayii kọja, ko sigba ti mo ri ẹ ti mi o ri ẹrin lẹnu rẹ. Mi o tiẹ mọ ohun ti mo fẹẹ sọ.’’
Ni nnkan bii ọsẹ mẹta sẹyin ni ọkan ninu awọn alawada to fi ilu Ibadan ṣe ibugbe ti wọn n pe ni mimic_king ku. Awọn adigunjale ni wọn yinbọn pa ọmọkunrin yii lẹyin ti wọn gba gbogbo owo ọwọ ẹ.