Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ, inu adanu nla ni awọn oniṣowo to n taja lawọn ṣọọbu meje kan lopopona Fasiti Ilọrin, lagbegbe Táńkẹ̀, niluu naa wa bayii. Ina lo jo awọn ṣọọbu ọhun gburugburu lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, kejila, oṣu Kejila yii.
ALAROYE gbọ pe kẹu- kẹu ni ina n jo awọn ọja to wa ninu awọn ṣọọbu meje ti wọn fẹgbẹkẹgbẹ, ti wọn ti n ta oniruuru ọja ni nnkan bii aago marun-un aabọ irọlẹ ọjọ Iṣẹgun, ọṣẹ yii.
Gbogbo igbiyanju awọn araadugbo lati pa ina naa lo ja si pabo. Nitori wọn ko tete ri awọn panapana ke si lo mu ki ina ọhun bu gbamu si i titi to fi jo ṣọọbu meje naa kanlẹ.
Arakunrin kan to n gbe lagbegbe naa ṣalaye fun akọroyin wa pe ni nnkan bii aago marun-un aabọ irọlẹ ni ijamba ina naa bẹrẹ, ti gbogbo olugbe agbegbe ọhun si n gbiyanju agbara wọn lati pa ina ọhun kawọn panapana too de.
Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Alukoro ileeṣẹ panapana ni Kwara, Hassan Hakeem Adekunle, ni dukia to ṣofo nibi ijamba ina yii n lọ bii miliọnu mọkandinlogun ati igba Naira (19.2m). O ni ina ọhun lagbara kọja afẹnusọ, sugbọn ni kete ti ajọ panapana gunlẹ sibi iṣẹlẹ naa ni wọn kapa rẹ, ti wọn si pa a patapata ko maa baa ran mọ awọn ṣọọbu miiran to sun mọ ọn.
O tẹsiwaju pe ṣọọbu mẹtadinlogun lo wa nibi ile to n jona yii, meje pere lo jona gburugburu, ti ileeṣẹ panapana si doola mẹwaa yooku lọwọ ina.
Ọga ajọ pananapa ni Kwara, Ọmọọba Falade John Olumuyiwa, rọ gbogbo olugbe Kwara ki wọn maa wa loju ni alakan fi n ṣọri lọfiisi ati ninu ile, ki wọn si maa yago fun gbogbo ohun to le ṣokunfa ijamba ina layiika wọn.