Oke pa ọrẹ ẹ nitori ọọdunrun Naira

Monisọla Saka

Yoruba bọ, wọn ni owo ni i ba oju ọrẹ jẹ, bẹẹ ni ibinu ko mọ pe olowo oun ko lẹsẹ nilẹ. Inu abiju yii lo ko ba ọkunrin kan to n jẹ Godstime Oke, to tori apo kan aabọ Naira ran ọrẹ ẹ, Allia, lọ sọrun ọsan gangan. Oke ati ọrẹ ẹ, Ọgbẹni Gaga Allia, ti wọn jọ n gbele ni wọn ni ede aiyede bẹ silẹ laarin wọn latari ọọdunrun Naira owo Nepa ti wọn pin fun ile ti wọn n ya gbe, eyi to wa l’Ojule kejilelọgbọn, Opopona Ole, lagbegbe Okumagba, Warri, nipinlẹ Delta. Ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrinla, oṣu Kejila, ọdun yii, niṣẹlẹ buburu naa waye.

ALAROYE gbọ pe ọrẹ timọtimọ ni wọn pe Oke ati Allia ti wọn jọ n gbe nile oniyara kan ninu ile naa.

Oke ni wọn lo maa n gba owo ina jọ lọwọ gbogbo awọn ara ile, ko le baa rọrun lati ko o ni kiṣi fawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ mọnamọna lai ni i mu ariyanjiyan dani nigba ti wọn ba fẹẹ sanwo. Ṣugbọn lọjọ tiṣẹlẹ buburu yii maa waye, Oke ko si nile, nitori bẹẹ ni ọkan ninu awọn ti wọn jọ n gbele ṣe san ọọdunrun Naira (300) owo ina tiẹ fun ọrẹ ẹ, Allia, lati ba a fi jiṣẹ fun un to ba dari wọle. Nigba ti Oke pada dele lalẹ to beere owo ti wọn fi ran ọrẹ ẹ silẹ, niṣe ni Allia kọ jalẹ ti ko fun ọrẹ ẹ lowo ti wọn fi ran an silẹ.

Ọrọ owo yii ni wọn lo dija laarin awọn mejeeji, nibi ti wọn ti n ja  ni Oke ti ki ẹkufọ igo mọlẹ, to si fi gun ọrẹ ẹ nibi ọrun. Loju-ẹsẹ ni wọn lọkunrin naa ṣubu lulẹ, to bẹrẹ si i japoro, bẹẹ lẹjẹ n tu yaayaa nibi ọrun ẹ titi to fi ki aye pe o digbooṣe.

Nigba ti oju Oke walẹ to ri wahala to da bọ ara ẹ lọrun lo ki ere mọlẹ, diẹ lo si ku ki ọwọ awọn eeyan tinu n bi ti wọn n leri pe awọn maa pa a tẹ ẹ.

Adugbo Ugborikoko ti ko fi bẹẹ jinna sibi ti wọn n gbe ni wọn lo sa lọ lati lọọ fara sinko, nibẹ naa lọwọ si ti tẹ ẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kejila, ọdun yii. Nibẹ ni wọn ti fa a le awọn agbofinro teṣan ọlọpaa ‘B’ Division, niluu Warri lọwọ.

Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Delta, Bright Edafe, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, bẹẹ lo fi kun un pe iwadii ti bẹrẹ, awọn si ti n sapa lati mu Tega, to jẹ agbodegba afurasi ọhun.

Leave a Reply