Nitori pe okele àkọ́bù ki i rahun ọbẹ, lonii ọjọ akọkọ ninu ọdun tuntun yii, awa o ni i rahun owo, a o ni i rahun ọmọ, a o ni i rahun ibukun, a o ni i rahun alaafia ti i ṣe baalẹ ọrọ. Ire gbogbo, gbogbo ire, ni yoo jẹ tiwa ninu gbogbo idawọle wa ninu ọdun tuntun yii laṣẹ Edumare. Ẹ ku ọdun o.