Òkèlè nla to nira lati gbe mi ni iku Yinka Odumakin – Ọọni

Florence Babaṣọla

 

Arole Oduduwa to tun jẹ Ọọni ti Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, Ọjaja 11, ti ṣapejuwe Oloogbe Yinka Odumakin gẹgẹ bii ẹni ti itan ko le gbagbe ipa takuntakun to ko ninu ọrọ ijọba tiwa-n-tiwa lorileede yii.

Ninu ọrọ ibanikẹdun ti Akọwe iroyin Ọọni, Moses Ọlafare, fi sita ni kabiesi ti sọ pe iku ọkunrin naa ba oun lojiji, nitori o ku lasiko ti iran Yoruba, paapaa, orileede Naijiria, nilo rẹ ju.

O ni okele nla to nira lati gbe mi ni iku rẹ jẹ fun Ile Oduduwa, nitori adari ilẹ Yoruba to ni ẹmi ikora-ẹni-nijaanu, to si jẹ akekaka kọlọrọ o gbọ lọkunrin naa lorileede yii.

Ọọni sọ siwaju pe Odumakin sin iran Oodua lai dibajẹ titi to fi ku, o si mu ijọba tiwa-n-tiwa gbooro lorileede yii nipasẹ bo ṣe maa n ke fun idajọ ododo ati kijọba ṣe nnkan to tọ lai role apa kan da apa kan si, ti ko si mọ tara rẹ nikan.

Gẹgẹ bii agbẹnusọ fun ẹgbẹ Afẹnifẹre ti ko bẹru ẹnikankan, Ọọni sọ pe Odumakin ko figba kankan gboju kuro lara ohun to ba ro pe ko dara to tijọba Aarẹ Buhari ba ṣe lai tiẹ ro ti ibaṣepọ to ti wa laarin wọn ri.

Ọọni Ogunwusi ni alafo nla ni iku ọkunrin naa fi silẹ, o si waa di dandan bayii lati tẹle ipa rere to ti la silẹ fun igbesi aye irọrun fun gbogbo awọn eeyan orileede Naijiria.

Kabiesi gbadura pe ki Ọlọrun tu iyawo oloogbe naa ninu, ko si fun awọn mọlẹbi rẹ lokun lati la asiko to lagbara yii kọja.

 

Leave a Reply