Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Oju ọna marosẹ Ṣagamu-Ijẹbu-Ode lawọn ọkunrin meje yii ti maa n ṣọṣẹ. Awọn tirela akẹru to n bọ lati awọn ileeṣẹ kaakiri ni wọn maa n da lọna, ti wọn yoo si gba gbogbo ohun ti wọn ba n ko lọ naa ati tirela, pẹlu nnkan ogun ni wọn n ṣiṣẹ laabi wọn.
Gẹgẹ bawọn ọlọpaa ṣe kọ ọ, orukọ wọn ree: Onyegbuchi Nwafor, Idakole Benjamin, Ibrahim Musa, Abọlade Shọla, Ikem Ejimofor, Adebayọ Jamiu ati Adeyẹye Edwin.
Iru iṣẹ bẹẹ ni wọn n ṣe lọwọ lọjọ kẹjọ, oṣu kejila, ọdun 2021, ti ipe fi dun ni teṣan ọlọpaa Odogbolu, ni nnkan bii aago mẹta oru, pe awọn adigunjale ti ja tirela kan to ko ọja ileeṣẹ kan lọna.
Wọn ni niṣe lawọn ole naa so dẹrẹba to wa tirela naa lokun pẹlu ọmọ ẹyin ọkọ ti wọn jọ n lọ, inu igbo ni wọn lọọ de wọn mọ ti wọn si gbe tirela ẹlẹru naa lọ.
Awọn ọlọpaa lọ sibẹ, ṣugbọn wọn ko ba awọn adigunjale yii mọ, wọn bẹrẹ si i dọdẹ wọn pẹlu apejuwe tawọn eeyan to ri wọn ṣe, nigba to si ya, wọn ri tirela akẹru naa to fẹẹ kọja si oju ọna Ijẹbu-Ode.
Kia lawọn ọlọpaa bẹrẹ si i le wọn, wọn ri awọn mẹta mu, awọn mẹrin sa lọ ninu ọkọ ayọkẹlẹ Honda kan.
Afi bo ṣe di laaarọ ọjọ naa gan-an ti awọn to sa lọ gba lọọya, ti wọn sọ fun un pe awọn ọlọpaa ti mu awọn ọrẹ awọn laiṣẹ, ti wọn ni ki lọọya naa bawọn gba beeli Musa Ibrahim, Shọla Abọlade ati Edwin Adeyẹye tọlọpaa mu n’Ijẹbu-Ode.
Gẹgẹ bi alaye DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, o ni awọn ọlọpaa sọ fun lọọya pe ko lọọ ko awọn to ran an niṣẹ wa kawọn too le fi awọn to wa lahaamọ naa silẹ.
Nigba naa ni lọọya pe wọn lori aago pe ki wọn maa bọ o, awọn ti fẹẹ yanju ọrọ. N ni Nwafor Onyebuchi ati Idakole Benjamin tawọn naa jẹ sajẹnti ọlọpaa tẹlẹ ki wọn too le wọn danu ba yọju si teṣan, bi wọn ṣe mu wọn silẹ niyẹn.
Wọn ko wọn lọ sẹka SCID ti wọn ti n ṣewadii kikun, wọn fọrọ wa wọn lẹnu wo, ni wọn ba jẹwọ pe awọn lawọn di oju ọna marose, tawọn gba tirela to ko Blue band sinu naa lọwọ dẹrẹba ati ọmọ ẹyin ọkọ, tawọn si so wọn mọlẹ bii ẹran.
Wọn tun jẹwọ pe awọn ti da tirela mẹrin lọna ri tawọn ti gba awọn ọja bii ‘Pampers, nnkan mimu Nutri C, Blue band ati fulawa Honey well. Apapọ owo ọja ti wọn ti ja gba yii si jẹ miliọnu mẹẹẹdọgbọn o le ẹgbẹta ati diẹ (25,688,000).
Nipa bi wọn ṣe n ṣe ọja ti wọn ba jagba naa, wọn ni Alaaji kan lawọn n ta a fun ni Kwara, ẹni naa ni Alaaji Jamiu. Bawọn ọlọpaa ṣe dọdẹ ẹ ti wọn wa a de Ẹrin-Ile, ni Kwara, niyẹn ti wọn si mu un.
Alaaji Jamiu naa jẹwọ, o loun loun ni tirela tawọn adigunjale yii fi dabuu ọna nibi iṣẹ ti wọn ṣe gbẹyin, bẹẹ ni Ikem Ejimofor naa jẹwọ pe oun naa maa n ra awọn ọja yii lowo pọọku ti ko ṣee gbọ seti.
Ọga ọlọpaa Ogun, CP Lanre Bankọle, dupẹ lọwọ awọn ọlọpaa to ṣiṣẹ takun-takun ti wọn fi ridi awọn adigunjale yii, bẹẹ lo ni ko gbọdọ pẹ rara ti wọn yoo fi foju bale-ẹjọ.