Lasiko ti a n kọ iroyin yii, awọn ọlọpaa ṣi n wa Alfred Kigena, ọkunrin ọmọ orilẹ-ede Kenya to da tii gbigbona lu iyawo rẹ labẹ, nitori iyẹn wo foonu rẹ, o si ka atẹjiṣẹ ti ale fi ranṣẹ sọkọ rẹ yii.
Agbegbe Kericho, ni Kenya, niṣẹlẹ yii ti waye lọsẹ to kọja, obinrin to si ṣẹlẹ si ni Sharon Chepkorir, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn (25).
Funra Sharon lo sọ ọ di mimọ fawọn akọroyin pe lọjọ Sannde, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹjọ, ọdun 2021, ọkọ oun, Alfred, ẹni ọdun mejilelọgbọn (32) wọle sinu yara, o si ba oun pẹlu foonu rẹ lọwọ, nibi toun ti n kọ nọmba obinrin kan to fi atẹjiṣẹ ranṣẹ si i silẹ.
“Ọkọ mi beere pe kin ni mo n fi foonu oun ṣe, mi o da a lohun, bo ṣe gbe tii to wa lori ina niyẹn, o si da a lu mi. Tii gbigbona naa da si abẹ mi, o bo mi loju ara, itan ati apa kan ẹsẹ mi naa si bo, mi o le jokoo daadaa bayii” Bẹẹ ni Sharon ṣalaye nile baba rẹ to ko lọ lẹyin iṣẹlẹ naa.
Fidio kan ti ẹka iroyin The Standard ni lọwọ ṣafihan awọn ibi to ṣee fi han lara obinrin naa, bẹẹ ni ko le jokoo daadaa loootọ.
Ọkan lara awọn mọlẹbi Sharon, Ọgbẹni David Yegon, ṣalaye pe awọn tọkọ-taya yii maa n ja lọpọ igba, awọn maa n ba wọn da si i ṣugbọn ki i si iyatọ kan, wọn yoo ṣaa maa ṣe bii ologbo ati eku ni.
O ni pẹlu eyi ti ọkọ aburo oun ṣe yii, afi kijọba ba wọn da si i, nitori ẹ lawọn ṣe fi iṣẹlẹ naa to wọn leti, to fi di pe wọn kede Alfred to ti sa lọ bii ẹni ti wọn n wa.