Ọkọ mẹrin fori sọra wọn lori biriiji Kara, eeyan kan ku

Jọkẹ Amọri

Nidaaji Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu Keji yii, ni ijamba ọkọ kan ṣẹlẹ, nibi ti awọn mọto mẹrin kan ti fori sọra wọn, ti ẹni kan si ku lẹsẹkẹsẹ lori biriiji Kara, to wa loju ọna marosẹ Eko s’Ibadan.

Gẹgẹ bi awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣe fi to ALAROYE leti, wọn ni mọto elero mejidinlogun kan to jẹ ti ileeṣẹ GUO motors, ọkọ Sienna kan, Toyota Corolla ati Toyota Matrix kan ni ijamba ọhun kan.

Ọkọ ajagbe kan ni wọn lo sọ ijanu rẹ nu, lo ba lọọ sọ lu awọn ọkọ to wa lẹyin rẹ yii, eyi lo si mu ki Toyota Matrix naa ja bọ si odi keji lati ori biriiji naa, ti ọkọ jiipu Toyota to sọ mọ yii si run womuwomu.

Ọkan ninu awọn to maa n taja ninu gosiloo loju titi naa la gbọ pe o padanu ẹmi rẹ lasiko ijamba ọhun.

Ijamba ọkọ naa ti mu ko nira fun awọn ọkọ lati rin geere lasiko ti a n kọ iroyin yii. Niṣe ni igboke gbodo ọkọ duro tiiri bii omi ọka, ti awọn to fẹẹ kọja siluu Eko lati ori biriiji Kara naa ko si ribi lọ.

A gbọ pe awọn ẹṣọ oju popo ati ileeṣẹ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri (LASEMA) ti wa nibẹ lati palẹ awọn mọto naa mọ ati lati dari oju ọna ki awọn ọkọ le maa raaye lọ geerege.

Bakan naa ni wọn ti ko awọn to fara pa ninu ijamba naa lọ si ọsibitu.

 

Leave a Reply