Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn pere (25) ni Lubabatu Ibrahim, obinrin to ṣi duro deede, to si ni agbara ibalopọ daadaa ni. Ṣugbọn ọkọ to fẹ, Habibu Ibrahim, ko mọ kinni naa ṣe i rara, iṣẹju meji pere lo n fi n damira ni tiẹ, ohun to mu iyawo rẹ gba kootu lọ niyẹn, to ni oun ko fẹ ẹ mọ.
Kootu Ṣẹria ni Lubabatu gbe ọkọ rẹ lọ lọjọ Iṣẹgun, lagbegbe Rigasa, ti wọn n gbe, ni Kaduna. Nibẹ lo ti ṣalaye pe oun ko mọ bi ọkunrin yoo ṣe wa ti ko ni i le gbo oun mọlẹ ki ara oun ya gaga.
O ni bi Habibu ba bẹrẹ tiẹ bayii, iṣẹju meji pere ni, yoo ti sare da ti ọwọ rẹ silẹ, ni yoo ba maa han-an-run oṣi kan lẹgbẹẹ oun, bẹẹ, oun ṣẹṣẹ bẹrẹ si i gbadun ara oun ni toun ni, ko si sohun toun yoo ṣe si kinni Habibu lati dide pada, ko ni i dahun, yoo dori kodo bii ẹrọ afami ni.
O ni loootọ, awọn ti bimọ ẹyọ kan o, ṣugbọn iyẹn kọ ni koko. Ọna ati bimọ mi-in gan-an da nigba ti kinni ọkọ oun ko ka oun lẹnu.
O loun si ti gba a nimọran titi pe ko lọọ wa nnkan ṣe si ọrọ ara rẹ, ko dahun, ko tiẹ ja a kunra.
Ki i ṣe eyi nikan niṣoro Habibu gẹgẹ bi iyawo rẹ ṣe wi, Lubabatu ni were diẹdiẹ wa lara ọkọ oun yii. O ni aisan kan ti wọn n pe ni ogun oru, eyi to maa n mu ori gbona, ti ẹni to n da laamu yoo deede maa pariwo gee lọwọ alẹ ati oru n ṣe Habibu.
O ni ti kinni naa ba ki i bayii, yoo maa pariwo gee ni, igba mi-in si wa ti yoo maa ṣe bii were, ti yoo maa da gbogbo nnkan ru ninu ile, ti yoo si maa ba awọn nnkan mi-in jẹ.
Gbogbo awọn nnkan wọnyi lo ni o jẹ ki igbeyawo yii su oun, toun si ṣe fẹ ki kootu Ṣẹria tu awọn ka labẹ ofin naa.
Nigba to n ṣalaye tiẹ, Habibu sọ pe oun ṣi nifẹẹ iyawo oun, oun ko ṣetan lati kọ ọ. Ọkunrin naa ni ko si irọ kankan ninu awọn ẹsun meji tiyawo oun fi kan oun yii, bo ṣe ri gẹlẹ lo sọ ọ yẹn.
O ni ṣugbọn ki i ṣe pe oun dakẹ bẹẹ naa, oun ti n wa oogun ibilẹ ti yoo tọju aileṣe-deede oun lori ibusun, oun si ti n lọ si ileewosan awọn alaisan ọpọlọ lati ri si ti ọdẹ-ori to n daamu oun.
Malam Salisu Abubakar Tureta lo gbọ ẹjọ naa, o paṣẹ pe kawọn tọkọ-taya naa pada sile lọdọ awọn ẹbi wọn, ki wọn ba wọn da si i. O ni ki wọn pada wa lọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹsan-an yii.