Ọkọ mi o lowo lọwọ, emi ni mo n gbọ gbogbo bukaata ninu ile, ẹ tu wa ka- Bashirat 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Iwaju onidaajọ Hammad Ajumọbi, tile-ẹjọ kọkọ-kọkọ kan ti wọn n pe ni Area-Court, to wa ni Centre-Igboro, niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara, ni awọn tọkọ-taya meji kan, Abilekọ Bashirat Mohammed ati ọkọ rẹ, Ọgbẹni Toyin Ajibọla, gbe ara wọn lọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2024 yii. Ẹsun ti Abilekọ Bashirat ti i ṣe olupẹjọ fi kan ọkọ rẹ ni pe ko lowo lati maa fi ṣetọju oun pẹlu awọn ọmọ toun bi fun un.

O ni, ‘‘Oluwa mi, ọrọ mi ko pọ rara, ohun ti mo n fẹ gan-an ni pe kile-ẹjọ yii tu igbeyawo to wa laarin emi pẹlu ọkọ mi ka, ki kaluku wa maa lọ ni ayọ ati alaafia, mi o ṣe mọ. Ko sifẹẹ kankan laarin awa mejeeji mọ.

Mi o le ranti igba ti ọkọ mi ti ṣojuṣe rẹ ninu ile lori awọn ọmọ tabi lori emi paapaa ti mo jẹ iyawo rẹ. Mo n fẹ ki wọn tu wa ka loju-ẹsẹ ni, ki n le ni ifọkanbalẹ, mo ti ro o titi, mi o ri i ro mọ. Emi yii nikan ni mo n da gbọ gbogbo bukata inu ile pata, bawọn ọmọ wa ba nilo nnkan, emi ni mo n ṣe e fun wọn”.

Nigba to n dahun si ẹsun tiyawo rẹ fi kan an, Ọgbẹni Ajibọla ni oootọ ni ẹsun tiyawo oun fi kan oun yii, ṣugbọn ki wọn ba oun bẹ ẹ pe ko fọwọ wọnu lori ohun to n bi i ninu s’oun, o ni oun naa n gbiyanju agbara oun lati wa owo, ṣugbọn pabo lo n ja si. Baale ile yii ni eyi to n dun oun ju ninu ọrọ yii ni pe oun o ki i rowo lati maa lọ sọdọ iyawo oun atawọn ọmọ nigba ti wọn kuro nile.

‘‘Ẹ ba mi bẹ ẹ pe ko ma binu si mi, mo ṣi nifẹẹ iyawo mi gidi. Mo fi da a loju pe laipẹ, gbogbo nnkan n bọ waa pada daa fun wa ninu ile.

Ninu idajọ rẹ, Onidaajọ Hammad Ajumọnbi, ni ki awọn ọmọ mẹtẹẹta ti wọn bi fun ara wọn wa labẹ akoṣo iyawo, ki ọkọ si maa ṣe ojuṣe rẹ nipa pipeṣe ohun ti wọn o maa jẹ bi agbara rẹ ṣe mọ o si tu igbeyawo naa ka.

 

Leave a Reply