Adewale Adeoye
Awọn agba bọ, wọn ‘ọrọ to n pa oloko lẹkun ni aparo fi n ṣẹrin-in-rin’. Bẹẹ lọrọ ri nile-ẹjọ kọkọ-kọkọ kan to wa lagbegbe Mapo, niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrin, oṣu Kẹjọ, ọdun 2023 yii, nigba tiyawo ile kan, Abileko Ayisat Surajudeen, n rojọ ohun toju rẹ ri lọdọ ọkọ to bimọ mẹta fun.
Ayisat n bẹ adajọ ile-ẹjọ naa, Onidaajọ S.M Akintayọ, pe ko ba oun tu igbeyawo ọlọdun gbọọrọ to wa laarin oun ati ọkọ oun, Tajudeen, ka, ki adajọ si faaye gba oun lati maa ṣetọju awọn ọmọ awọn lọ. Bẹẹ lo ni ki wọn paṣẹ fọkọ oun lati maa san owo ounjẹ awọn ọmọ naa atawọn ohun miiran ti wọn ba nilo nigba gbogbo.
Nigba to n ṣalaye idi to fi fẹẹ kọ ọkọ rẹ silẹ, iyaale ile yii sọ pe bii aṣọ ofi lọkọ oun maa n lu oun nigba gbogbo tija ba bẹ silẹ laarin awọn, iya naa si pọ debii pe ara oun ti kọ ọ bayii.
‘‘Yato si pe ọkọ mi maa n lu mi bii baara nigba gbogbo, igba kan wa to waa ka mi mọ ṣọọbu ti mo ti n taja, o waa ko ọja atowo ọja ti mo ta lọjọ naa lọ.
‘Ki i ṣojuṣe rẹ ninu ile, emi yii kan naa ni mo n da gbọ gbogbo bukaata ile. Ẹ ba mi kilọ fun un pe ko ma de sakaani mi mọ rara, mi o fẹẹ ri i, inu rẹ n bi mi. ‘Ero ọtọ lo wa lọkan mi nipa igbeyawo, ṣugbọn nigba ti mo fẹ ọkọ mi tan ni mo too mọ pe ọja okunkun ni wọn n pe ni igbeyawo. Loooto a ṣegbeyawo ibilẹ, ọkọ mi si san Naira mẹta pere gẹgẹ bii owo-ori mi fawọn obi mi, mo ti bimọ mẹta fun un, ṣugbọn latigba ti mo ti ko de’le rẹ, ko si igbadun kankan fun mi. Ṣe ni mo n ṣiṣẹ bii akura lati ṣetọju awọn ọmọ wa, nigba ti wahala naa fẹẹ pọ ju ni mo kẹru jade nile fun un, ti mo si lọọ gba ile siluu Ibadan. Ko rọrun fun mi lakooko yii lati maa ṣetọju awọn ọmọ wa mẹtẹẹta, paapaa ju lọ eto ẹkọ wọn. Ẹ jọọ, Oluwa mi, ẹ sọ fun un pe ko maa ran mi lọwọ lori awọn ohun gbogbo tawọn ọmọ wa nilo.
Nitori pe Ọgbẹni Tajudeen ti i ṣe ọkọ Ayisat ko si nile-ẹjọ lọjọ yii lo mu ki adajọ ile-ẹjọ naa, Abilekọ S.M Akintayo, sun igbẹjo siwaju, to si paṣẹ fun akọwe ile-ẹjọ naa lati lọọ fun ọkọ Ayisat niwee ipẹjọ, ko le yọju si kootu.