Stephen Ajagbe, Ilorin
Abdulwasiu Ọmọ-Dada, ọkọ obinrin toun atawọn ọmọ rẹ ni ẹyin oju to yatọ, Risikatu Abdulazeez, ti loun ko kọ obinrin naa silẹ nitori ẹyin oju rẹ ati tawọn ọmọ rẹ to yatọ.
O ni nitori ẹyin oju rẹ gan-an loun ṣe fẹ ẹ. O lo waa ya oun lẹnu bo ṣe n sọ kiri pe oun le e jade nile.
Wasiu ṣalaye pe nigba tawọn ri ara awọn, oun nifẹẹ rẹ, oun si gba ọna to tọ lọ lati fẹ ẹ sile.
Baale ile yii ni nigba to bimọ akọkọ tiyẹn naa si gbe iru ẹyin oju rẹ waye, oun ko tori rẹ pa a ti, tabi sa lọ fun un. O ni ẹgbẹrun marundinlogoji loun tu jọ lati fi sanwo ileewosan nigba naa.
Baale ile yii ni awọn obi Risikatu lo maa n sọ pe oun n fiya jẹ ọmọ awọn, ṣugbọn ko ri bẹẹ. O ni oun maa n ra ounjẹ sile, oun si n ṣe iwọnba ti agbara oun mọ lati maa tọju rẹ.
Wasiu ni o ṣi n ya oun lẹnu bi wọn ṣe n gbe e kiri pe oun kọ ọ silẹ. O loun gba pe ohun to fẹẹ fi san ifẹ toun ni si i niyẹn, oun si ti gba f’Ọlọrun.
Ṣugbọn, Risikatu ni irọ patapata ni Wasiu n pa. O ni lẹyin toun bi awọn ọmọ mejeeji lawọn obi rẹ ko si i ninu, to si bẹrẹ si i ṣiwa-hu soun.
“Ko ni i wa sile, ko tun fowo ounjẹ silẹ. Ṣe lo yipada si mi patapata”.