Faith Adebọla, Eko
Ọmọ bibi ipinlẹ Imo ni wọn pe Wisdom Okoro yii, bẹẹ ni ki i ṣe ọmọde rara, o ti dẹni aadọta ọdun, ṣugbọn pampẹ ofin to mu un lasiko yii lagbara gan-an, tori ẹsun ti wọn fi kan an ni pe oun lo ṣokunfa iku ọrẹbinrin ẹ, Enobong Udoh. Wọn ni ibi tọmọbinrin ẹni ọdun mejidinlogoji naa ti lọọ ṣẹyun to loun ni fọkunrin ọhun lẹmi ti bọ lara ẹ, to fi doloogbe.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, DSP Olumuyiwa Adejọbi, to fiṣẹlẹ yii to ALAROYE leti sọ pe nnkan bii aago mẹwaa aabọ owurọ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanla, oṣu yii, niṣẹlẹ ibanujẹ naa waye n’Ikorodu.
Ọrẹ oloogbe naa, Blessing Pius, ni wọn lo pe ara ẹ, Ojule kẹrindinlaaadọta, Opopona Adegboruwa, ni Igbogbo, lagbegbe Ikorodu, lo loun n gbe, oun lo ṣalaye ohun to ṣẹlẹ fawọn ọlọpaa. O ni niṣe lawọn ba oku ọrẹ oun, Eno, gẹgẹ bii ikekuru orukọ ẹ, ninu yara ẹ nile to doju kọ otẹẹli Meras, to wa lọna Igbogbo kan naa, lo ba lọọ fi to awọn ọlọpaa leti.
O ṣalaye fawọn ọlọpaa pe ko ti i pẹ ti afurasi ọdaran Okoro kuro lọdọ ọrẹbinrin ẹ to doloogbe yii, ẹyin to kuro lo jẹ oku obinrin naa ni wọn ba.
Loju-ẹsẹ lawọn ọlọpaa atawọn ọtẹlẹmuyẹ ti tẹsẹ bọ iṣẹlẹ naa, wọn wa Okoro bii igba tobinrin n wa nnkan ọbẹ, ọwọ wọn si tẹ ẹ, ni wọn ba mu un lọ si teṣan wọn.
Wọn lo jẹwọ fawọn ọlọpaa pe loootọ ni Eno jẹ ọrẹbinrin oun, awọn si ti n fẹra awọn bọ ilẹ ti ta si i, ati pe ni tododo, oloogbe naa sọ foun ninu oṣu keji, ọdun yii, pe oun ti loyun foun.
O loun o sọ fun un pe ko lọọ ṣẹyun o, oun o si mọ bo ṣe ṣe e to fi lọọ ṣẹyun ọhun. Okoro ni ọjọ Abamẹta, Satide, loun de ọdọ ẹ kẹyin, o ni ọjọ Satide naa lọrẹbinrin oun to doloogbe yii sọ foun pe oun ti lọọ yọ kinni ọhun danu, ati pe ara oun n ṣe bakan bakan, o loun si ṣaajo ẹ. Ọk unrin yii ni aago marun-un kọja iṣẹju mẹrinla loun ti kuro nibẹ ni toun, oun si ti lọ sile.
Ṣugbọn awọn aladuugbo ati ọrẹ oloogbe naa sọ fawọn ọlọpaa pe irọ ni Okoro n pa, wọn lo mọ nipa iku oloogbe naa, wọn si lawọn ri i nibẹ laaarọ ọjọ tiṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.
Ṣa, awọn ọlọpaa ti fi pampẹ ọba gbe Okoro, wọn si ti gbe oku oloogbe lọ si mọṣuari fun ayẹwo lati mọ ibi ti iku ẹ ti wa. Awọn ọlọpaa ni Okoro ṣi ni alaye pupọ to gbọdọ ṣe fawọn, tori ẹ, wọn ti fi i ṣọwọ sẹka ọtẹlẹmuyẹ, nibi ti wọn ti n ṣewadii iwa ọdaran abẹle ni Panti, Yaba.
Adejọbi ni tawọn ba ti pari iwadii yii, gbogbo ẹjọ to ku di kootu.