Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejidinlogun, oṣu yii, ni awọn alaṣẹ ileewosan olukọni Fasiti Ilọrin, (UITH), nipinlẹ Kwara, paṣẹ pe ki wọn gbe oku baba kan to ku sileewosan naa, Alaaji Saliu atọmọ rẹ sahaamọ fẹsun pe ọmọ naa lu dokita kan lalubami, o ni ko tete tọju baba naa lo fi ku.
ALAROYE gbọ pe lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, ni ọkan ninu awọn ọmọ mẹta ti oloogbe fi saye lọ lu dokita naa lalubami ni yara ti wọn ti n tọju awọn alaisan pajawiri to ba ni ijamba ọkọ nileewosan UITH Ilọrin. O ni dokita naa ko tete ya si baba awọn titi ti iyẹn fi gbẹmii mi. Ni kete ti wọn kede iku baba wọn ni wahala bẹrẹ nileewosan ọhun, ti mọlẹbi alaisan to ku yii bẹrẹ si i lu dokita lalubami, o fun un mọ ara ogiri, niṣe lo si mura lati gbẹmi dokita yii, ori lo ko o yọ.
Ọkan ninu aọn mọlẹbi yii sọ pe ni nnkan bii aago marun-un idaji ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni wọn sare gbe Alaaji Saliu lọ si ileewosan naa. O ni pẹlu gbogbo ẹbẹ ti awọn bẹ dokita naa pe ko tete ya si alaisan naa, pabo lo ja si, ko sẹni to da awọn loun. Ọkunrin yii ni iyalẹnu lo jẹ bi dokita kan ṣe bẹrẹ si i tọju rẹ lẹyin ti wọn ti fi ọpọlọpọ wakati ṣofo, ko si pẹ lẹyin eyi ni dokita kan waa tufọ iku baba naa. Eyi lo fa ibinu ti wọn fi lu dokita naa lalubami, tawọn alaṣẹ ileewosan naa si kọ lati yọnda oku. Wọn ni afi dandan ki wọn lọọ wa ẹni to lu dokita wa.
Arabinrin Elizabeth Ajiboye, to ba awọn oniroyin sọrọ lorukọ awọn alasẹ ileewosan naa sọ pe awọn dokita to wa labẹ ẹgbẹ Association of Resident Doctors of Nigeria (ARD), nileewosan naa n fi ẹhonu han fun bi wọn ṣe lu ọkan lara wọn, wọn ni awọn alasẹ ọsibitu naa ko gbọdọ gbe oku yii fun wọn, afi ti wọn ba mu mọlẹbi wọn to lu dokita wa, ki wọn si fi i jofin.
Arabinrin Ajiboye rọ gbogbo awọn araalu ki wọn yee ṣe akọlu sawọn oṣiṣẹ eleto ilera mọ tori pe yoo da kun iṣoro alaisan ti wọn gbe wa. O ni ju gbogbo ẹ lọ, awọn dokita to wa lẹnu iṣẹ nigba naa gbinyanju agbara wọn lati du ẹmi alaisan ti wọn gbe wa, ṣugbọn ẹpa o boro mọ.
Tẹ o ba gbagbe, ọsẹ diẹ sẹyin naa ni mọlẹbi obinrin kan to ku sileewosan ijọba, Federal Medical Centre, to wa niluu Abẹokuta, lu dokita kan lalubami nigba ti iyẹn lọọ tufọ iku obinrin naa fun wọn, bo tilẹ jẹ pe wọn ti sọ fun awọn mọlẹbi yii latilẹ pe Ọlọrun nikan lo le la ẹmi rẹ.