Ọkunrin ti wọn fi kindinrin ẹlẹdẹ paarọ tiẹ ti ku lẹyin oṣu meji ti wọn ṣiṣẹ abẹ fun un

Adewale Adeoye

Baale ile kan, Ọgbẹni Richard Slayman, ẹni ọdun mejilelọgọta ọmọ orileede Amẹrika kan ti awọn dokita oniṣegun oyinbo paarọ kindinrin rẹ pẹlu ti ẹran ẹlẹdẹ ti ku lẹyin oṣu meji ti wọn ṣiṣẹ abẹ ọhun fun un tan. Ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹta, ọdun yii, ni awọn dokita oniṣegun oyinbo kan lati ileewosan ‘Massachusetts General Hospital’, MGH to wa lorileede Amẹrika, fitan balẹ nipa bi wọn ṣe fi kindinrin ẹlẹdẹ paarọ ti eeyan.

Ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kejila, oṣu Karun-un, ọdun yii, ni awọn dokita ti wọn ṣiṣẹ abẹ ọhun fun un kede rẹ pe Slayman pada jade laye lẹyin oṣu meji tawọn ṣiṣẹ abẹ naa fun un tan.

Ṣa o, wọn ni iku rẹ ko ni nnkan an ṣe pẹlu kindinrin elẹdẹ ti wọn fi paarọ tiẹ rara, nitori pe  ki wọn too ṣiṣẹ abẹ ọhun fun oloogbe lo ti larun itọ ṣuga ati ẹjẹ riru lara, o si ṣee ṣe ko jẹ pe ọkan ninu awọn aisan ọhun lo ṣokunfa iku ojiji naa fun un.

Ki wọn too fi kindinrin ẹlẹdẹ paarọ ti oloogbe naa lo jẹ pe ọpọ igba lawọn dokita oniṣegun oyinbo ti yọ ẹya ara ẹranko lati fi rọpo teeyan, ṣugbọn ti ko so eeso rere kankan, ti oloogbe yii lo fi han pe o ṣee ṣe ki ẹya ara ẹranko ṣiṣẹ fun awọn eeyan, nitori pe loju-ẹsẹ ti wọn ṣiṣẹ abẹ naa tan ni ara oloogbe ti ya daadaa.

Lọdun 2018 ni wọn kọkọ paarọ kindinrin oloogbe pẹlu ti eeyan, ṣugbọn lẹyin ọdun marun-un ni kindinrin ọhun daṣẹ silẹ lojiji, eyi lo mu ki wọn gbiyanju lati lo ti ẹlẹdẹ fun un lọdun yii.

Lẹyin oṣu meji ti wọn ṣiṣẹ abẹ ọhun fun un tan ni nnkan naa deede ki i mọlẹ lojiji, kawọn eeyan si too mọ ohun to n ṣẹlẹ,  Slayman ti ku lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.

Awọn alaṣẹ ileewosan ti wọn ti ṣisẹ abẹ naa fun un ti fidi iku oloogbe mulẹ fawọn oniroyin, wọn ba awọn ẹbi rẹ kẹdun eeyan wọn to ku lojiji.

Leave a Reply