Ọkunrin to gbe obinrin to ku sinu ọtẹẹli lọ sibẹ ti dero atimọle ọlọpaa

Ọlawale Ajao, Ibadan

Pẹlu bi ẹni ti wọn fẹsun iku Adeshina Ọlayinka, obinrin oniṣowo n’Ibadan, kan ti ṣe fa ara ẹ le awọn agbofinro lọwọ, awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa.

Ọkunrin yii pẹlu Ọlayinka to jẹ ọrẹbinrin ẹ ni wọn jọ sun sinu yara kan naa lati alẹ Ọjọruu, Wẹsidee, mọju Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹrin, ọdun 2023 yii, nileetura kan ti wọn n pe ni Wetland Hotel, laduugbo Akobọ, n’Ibadan.

Ṣugbọn laaarọ kutu, ni nnkan bii aago mẹfa aarọ n lọọ lu, nigba ti ilẹ ko ti i mọ tan, lọkunrin ti wọn fi orukọ bo laṣiiri yii fi ọrẹbinrin rẹ silẹ ninu yara ti wọn jọ sun, ti oun si ba tirẹ lọ.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, oṣiṣẹ to wa ni yara igbalejo lasiko naa beere lọwọ ẹ pe ẹni ti wọn jọ sun sinu yara nkọ, onitọhun fesi pe ekeji oun ṣi n sun lọwọ, ati pe oun ni ibi pataki kan ti oun ni lati yara lọ ni toun loun ṣe n ṣaaju ẹ jade lọ.

Sibẹsibẹ, ara fu oṣiṣẹ otẹẹli naa, o si pe Ọlayinka lori foonu lati beere alaafia rẹ, ati pe njẹ o mọ pe ẹnikeji rẹ ninu yara naa ti fẹẹ maa lọ, o ni oun mọ nipa ẹ, oun paapaa kan fẹẹ sinmi diẹ ki oun too maa lọ ni toun ni.

Esi ti Khadi fun obinrin yii lo jẹ ki wọn fun ọrẹkunrin rẹ lanfaani lati maa ba tiẹ lọ, niwọn igba tobinrin naa ti fìdi ẹ mulẹ pe alaafia loun wa, ati pe oun mọ nipa lilọ to n lọ.

Ẹrọ amunapamọ (power bank) ti oṣiṣẹ otẹẹli yii ya obinrin onibaara rẹ yii niyẹn lọọ beere to fi bẹrẹ si i kanlẹkun, ṣugbọn ti ko rẹni da a lohun.

Eyi lo mu ki onitọhun lọọ fi ohun to n ṣẹlẹ to manija ileetura naa leti, ti manija si fi kọkọrọ yara ọhun to wa nipamọ ṣilẹkun, oku Ọlayinka ni wọn ba lori ibusun níbẹ.

Bi awọn alaṣẹ ileetura naa ṣe fi iṣẹlẹ yii to awọn ọlọpaa leti ni wọn pe ọrẹkunrin Ọlayinka, nitori onibaara wọn ti wọn mọ daadaa nibẹ ni.

Wọn ni bo ṣe gbọ pe ọrẹbinrin oun ku lo gba ileetura naa lọ, to si yọnda ara ẹ pe kí wọn fa oun le awọn ọlọpaa to n ṣewadii ọran naa lọwọ.

Wọn lo sọ pe lati alẹ ọjọ ti awọn ti de ileetura naa loloogbe ti sọ foun pe o rẹ oun, ati pe nitori aarẹ to n ṣe e loun ṣe fi i silẹ ninu yara ko le raaye sinmi daadaa nigba ti oun n jade kuro nikeetura naa.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ yii, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Adewale Ọṣifẹṣọ, fidi ẹ mulẹ pe awọn agbofinro ti bẹrẹ iwadii lati mọ iru iku to pa gbajumọ oniṣowo aṣọ naa.

Bakan naa lawọn alaṣẹ Wetland Hotel, ti fi gbogbo eeyan lọkan balẹ pe gbogbo ọna ti awọn mọ pata lawọn yoo tọ lati ran awọn agbofinro lọwọ lori iwadii ti wọn n ṣe lori iku onibaara awọn ọhun.

 

 

 

Leave a Reply