Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni wọn ni ọkunrin babalawo kan niluu Ikẹrẹ Ekiti, gbe iyawo pasitọ ijọ alaṣọ-funfun kan lọ si otẹẹli, lasiko ti wọn si n ṣere ifẹ lọwọ ni babalawo naa gbẹmi-in mi.
Latari bi awọn eeyan ṣe n sọ pe magun ni ọkunrin ti wọn n pe ni Ejiogbe yii lu lara iyawo Pasitọ Ajagunigbala lo mu ki akọroyin wa ba Araba Awo ilu Oṣogbo, Oloye Ifayẹmi Ẹlẹbuibọn, sọrọ lori iṣẹlẹ naa. Eyi ni ohun ti baba naa sọ.
ALAROYE: Ṣe magun ṣi wa loootọ?
Baba Ẹlẹbuibọn: Magun ṣi wa nitootọ, ṣugbọn awọn aisan kan wa to jẹ pe wọn jẹ mọ magun naa. Ṣugbọn ojulowo magun to n ṣiṣẹ gidi wa, o kan jẹ pe ọlaju ko jẹ kawọn eeyan ka a si mọ, magun ṣi wa bo ṣe yẹ ko wa.
ALAROYE: Njẹ o ṣee ṣe fun bawo lati ku iku magun?
Baba Ẹlẹbuibọn: Akọkọ, ẹ ni lati wadii pe ṣe ojulowo babalawo ni, tori ọpọlọpọ awọn eeyan ti wọn n peraa wọn ni babalawo ni wọn ki i ṣe babalawo, ẹni to ba ti n jawe, o le jẹ oniṣegun, o le jẹ adahunṣe, babalawo naa lawọn eeyan aa maa pe e, ẹni ti kinni yẹn ṣẹlẹ si ki i ṣe ojulowo babalawo, tori to ba jẹ babalawo to n da Ifa, to mọ Ifaa ki daadaa, yoo mọ pe ki i ṣe nnkan to yẹ koun ṣe lo ṣe yẹn. Ko ṣee ṣe keeyan ma lọrẹẹ obinrin, ṣugbọn ko wa maa ṣagbere, o ta ko iṣẹ to gbe lọwọ, ki i jẹ keeyan nilaari, lara awọn nnkan to maa daamu eeyan ni.
Ọkunrin yẹn le ma jẹ ojulowo babalawo, ọdọkunrin kan lo maa jẹ, ti wọn n ṣewe-ṣegbo kaakiri.
Bakan naa, ẹni to ba muṣẹ agbere lọkun-un-kundun, awọn ni wọn maa n ṣe “òhùnmọ̀”, ti wọn yoo ṣe nnkan lati fi mọ nnkan to ba wa lara obinrin, o le jẹ oruka ti wọn yoo fi wọ obinrin nikun, ẹlomi-in ti le sin gbẹrẹ rẹ sidii to jẹ pe ara rẹ o ni i le wọle to ba jẹ pe arun wa lara obinrin to fẹẹ ba sun.
ALAROYE: Njẹ ẹrọ wa fun magun?
Baba Ẹlẹbuibọn: Ẹrọ magun wa, to ba ṣe pe ibi ti wọn ti huwa yẹn ki i ṣe bii otẹẹli ti eleyii ti ṣẹlẹ, iru ọkọ obinrin yẹn ni wọn aa lọọ ba pe ko fun awọn lẹrọ, to ba si ti fun wọn lẹrọ ẹ, ko ni i de oju iku.