Monisọla Saka
Joly Tyang, ọkunrin ọmọ orilẹ-ede Cameroon kan, ti lọọ fa ara ẹ le awọn ologun ilẹ wọn lọwọ, lẹyin to pa iyawo ẹ, ati ọkunrin kan to pe ni ale obinrin naa tan.
Laaarọ kutukutu ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹrin ọdun yii, ni wọn niṣẹlẹ naa waye niluu Makak, agbegbe Nyong, l’Aarin-gbungbun orilẹ-ede naa.
Ọkunrin gbajumọ onimọto, to n na ilu Maka, si Yaounde, ti i ṣe olu ilu orilẹ-ede wọn yii, sọ pe oun gbẹmi awọn mejeeji lẹyin toun ka wọn papọ nibi ti wọn ti n ṣe ifẹkufẹẹ, n lo ba yọ ada ti awọn mejeeji, o si ṣa iyawo ẹ ọhun ati ọkunrin ti wọn jọ n ṣe kerewa lọwọ, o ṣa wọn ṣaka-ṣaka, titi tẹmi fi bọ lara awọn mejeeji patapata.
Lẹyin to ṣe tinu ẹ tan, toju ẹ walẹ, lo funra rẹ wakọ lọ si baraaki Eseka Gendamerie Brigade, to si jọwọ ara ẹ fawọn ṣọja to ba lẹnu iṣẹ, pe oun ti huwa ọdaran.
Tyang ṣalaye lasiko ti wọn n fọrọ wa a lẹnu wo, pe ada loun fi fibinu ṣa awọn mejeeji yanna-yanna, toun si fi oku wọn silẹ nirona toun pa wọn si.
Gẹgẹ bi owuyẹ kan ṣe sọ, o ni, “Tyang Joly, to jẹ ilu-mọ-ọn-ka awakọ lagbegbe naa, ṣiṣẹ laabi yii ni nnkan bi aago meji oru kọja iṣẹju mẹta, lẹyin to ka iyawo ẹ papọ pẹlu ọkunrin mi-in. Iyawo ni ọkunrin yii kọkọ fi ada ṣa yankan-yankan, lẹyin naa lo lọọ ba ọkunrin to pe ni ale iyawo ẹ yii, ada ọhun kan naa lo si fi pa ọkunrin naa, laarin iṣẹju bii meloo kan siraawọn”.
Ṣa, awọn ileeṣẹ tọrọ kan lorilẹ-ede naa, ti bẹrẹ iṣẹ iwadii ni pẹrẹu, lori iṣẹlẹ ibanujẹ naa.