Adewale Adeoye
Awọn agba bọ, wọn ni ọjọ gbogbo ni tole, ọjọ kan ni tolohun, bẹẹ gẹlẹ lo ri fun baba arugbo kan, Alagba Aremu Shojobi, ẹni ọgọrin ọdun, ti wọn mu pe, o n ṣowo egboogi oloro igbo ni Iyana Ipaja, nipinlẹ Eko, lọjọ Ẹti, Furaidee, ogunjọ, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii.
ALAROYE gbọ pe awọn araalu kan ti wọn mọ nipa okoowo egboogi oloro ti afurasi ọdaran naa n ṣe ni wọn lọọ fọrọ rẹ to awọn agbofinro leti, lawọn NDLEA ba lọọ fọwọ ofin mu un nile rẹ to wa ni Iyana Ipaja, nipinlẹ Eko.
Alukoro ajọ ọhun, Ọgbẹni Fẹmi Babafẹmi, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, sọ pe obitibiti apo to kun fun igbo ti wọn ko sinu apo ṣaka lawọn ba nile afurasi ọdaran naa.
Atẹjade kan ti wọn fi sita nipa iṣẹlẹ ọhun ni wọn ti ṣalaye pe, ‘‘Ọjọ Ẹti, Furaidee, ogunjọ, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, lọwọ palaba afurasi naa, Alagba Arẹmu Shojobi, oniṣowo egboogi oloro ṣegi, awọn kan lo tu aṣiri rẹ fun wa, a si lọọ fọwọ ofin mu un nile rẹ, o si ti jẹwọ pe ọdun kẹẹẹdọgbọn ree toun ti wa nidii okoowo egboogi oloro naa, lati ilu Cotonou, lorileede Benin, lo ni wọn ti maa n gbe e wa foun’’.
Alukoro ni awọn maa ṣewadii nipa afurasi ọdaran naa, lẹyin eyi lawọn maa foju rẹ bale-ẹjọ.