Faith Adebọla
Iku kọja arifin, ina ẹlẹntiriiki ko si ṣee foju di, tori tọhun le ma rẹnu royin ohun toju ẹ kan, gẹgẹ bii tọkinrin tẹnikan o ti i mọ orukọ ẹ ati pato ibi to n gbe yii, wọn lọkunrin naa ṣera ẹ lofo ẹmi nibi to ti n gbiyanju lati ji ẹrọ amunawa, tiransifọma agbegbe Ede-Oballa, niluu Nsukka, nipinlẹ Enugu tu, ibẹ ni ina mọnamọna ti ṣọọki ẹ, lo ba ku tuẹ.
Iṣẹlẹ yii la gbọ pe o waye lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, ọjọ ọja kan ti wọn n pe ni Eke, lọjọ ọhun bọ si, inu ọgba ileewe Girl’s Community Secondary School, lagbegbe naa ni tiransifọma yii wa, ibẹ niṣẹlẹ naa ti waye.
Awọn obinrin ti wọn n dari bọ lati ọja nirọlẹ ni wọn ṣakiyesi oku ọkunrin afurasi adigunjale ọhun, nibi ti ina ẹlẹntiriiki gbe e sọnu si, nigba ti ina ṣọọki ẹ latara transifọma naa, ni wọn ba ke sawọn agbaagba ilu, kọrọ too di tọlọpaa.
Nigba tawọn araalu naa debẹ, gẹgẹ bi ẹnikan tiṣẹlẹ naa ṣoju ẹ, ṣugbọn ti ko fẹ ka darukọ oun ṣe wi, o ni wọn ba oku afurasi ọdaran yii pẹlu awọn irinṣẹ ti wọn fi n tu ẹrọ to ko wa ati apamọwọ alawọ kan, wọn lo tiẹ ti tu apa kan tiransifọma naa, ko too lu gudẹ.
Ẹni naa sọ pe niṣe ni ọkan ninu apa ọkunrin yii dudu fẹfẹ bii ẹran sisun, wọn lo jọ pe ọwọ to dudu ọhun lo fi mu irinṣẹ to fi n tu ẹrọ amunawa naa lọwọ ko too lu gudẹ.
Wọn ni niṣe lọkunrin yii fo fẹnsi wọnu ile kotopo ti wọn gbe tiransifọma naa si, tori titi pa ni ilẹkun ile naa wa, wọn si ri apa bulọọku to fọ, boya nigba to fẹẹ wọle ni o, tabi nigba ti ina gbe e lojiji.
Ọkunrin naa ni o ti to bii ọjọ meloo kan ti ko ti si ina ẹlẹntiriiki laduugbo naa, wọn lo le jẹ eyi lo tubọ ki afurasi yii laya to fi gbidanwo igbesẹ to ṣeku pa a lojiji ọhun.
Ṣa, awọn ọlọpaa lati teṣan wọn to wa ni Ede-Oballa, ti waa gbe oku afurasi yii kuro, pẹlu awọn irinṣẹ rẹ.